Igbimọ Agba ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun ti sọ pe irọ to jinna soootọ ni iroyin tawọn ọmọ ẹgbẹ Accord n gbe kaakiri pe ipade lori ọna lati ṣe eru ibo oṣu Kẹjọ lawọn lọ ṣe niluu Ila lọsẹ to kọja.
Gẹgẹ bi alaga wọn, Ẹnjinia Ṣọla Akinwumi, ṣe ṣalaye, o pọn dandan lati sọrọ lori ahesọ naa eleyii ti alaga ẹgbẹ Accord l'Ọṣun, Victor Akande, bẹrẹ rẹ, ko ma baa ṣi awọn araalu lọna.
Oloye Akinwumi sọ pe ile oun lawọn ti maa n ṣepade oloṣooṣu ọhun niluu Ilobu, ṣugbọn awọn pinnu lati gbe ti oṣu Kẹfa lọ sile Oloye Bisi Akande niluu Ila-Ọrangun lọjọ Kọkandinlogun oṣu Kẹfa.
O ni ọpọlọpọ awọn agbaagba ti wọn ṣe laalaa lori idasilẹ ipinlẹ Ọṣun ni wọn wa nibi ipade ọjọ naa, o si ṣeni laaanu pe awọn ti ko mọ nipa wahala awọn baba yii lori ipinlẹ Ọṣun le maa sọrọ ṣakaṣaka to le da wahala silẹ bẹẹ.
Oloye Akinwumi sọ siwaju pe loootọ ni Ọmọọba Adeleke Adebayọ ati Ẹnjinia Rẹmi Ọmọwaye jẹ eekan ninu ẹgbẹ oṣelu APC, ṣugbọn wọn ko si nibi ipade ọjọ naa, bi ẹgbẹ Accord si ṣe ran orukọ wọn mẹnu fi han pe ofo ni ahesọ ti wọn n gbe kaakiri.
'Ọrọ nipa itẹsiwaju ẹgbẹ APC nipinlẹ Ọṣun la sọ nibẹ, ki i ṣe ọna lati ṣe magomago ibo gomina ọjọ Kẹẹẹdogun, oṣu Kẹjọ ọdun yii. A rọ awọn araalu lati kọ etiikun si iroyin naa, ki wọn si mọ pe nnkan ti ẹgbẹ Accord fẹẹ ṣe ni wọn n parọ rẹ mọ wa yẹn.
'Mo tun rọ awọn ẹṣọ alaabo lati tete dide dojukọ ọnakọna ti awọn ọmọ ẹgbẹ Accord ba fẹẹ gba lati da wahala silẹ nipinlẹ Ọṣun, bẹẹ ni mo tun ke si awọn araalu lati tubọ maa ṣatilẹyin fun oludije wa, Aṣiwaju Munirudeen Bọla Oyebamiji fun idibo gomina to n bọ''

No comments:
Post a Comment