IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 16 June 2026

Kọmiṣanna Oyetọla, Yẹmi Lawal kọwe fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ l'Ọṣun



Kọmiṣanna fun ọrọ ọdọ ati ere idaraya lasiko iṣejọba Alhaji Gboyega Oyetọla nipinlẹ Ọṣun, Lawal Azeez Ọlayẹmi, ti kọwe fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ bayii.

Yẹmi Lawal, ẹni to jẹ ọkan lara awọn ọmọlẹyin Ọtunba Iyiọla Omiṣore lo kọ lẹta ranṣẹ si alaga APC ni wọọdu rẹ nijọba ibilẹ Iṣọkan, lọjọ kẹẹẹdogun oṣu kẹfa ọdun yii pe ki wọn yọ orukọ oun kuro ninu rẹgisita ẹgbẹ.

O ni oun gbe igbesẹ naa lẹyin ifikunlukun pẹlu awọn eeyan oun ati lẹyin ti oun ronu nipa ọjọọwaju oun ninu oṣelu.

O dupẹ lọwọ awọn agbaagba ẹgbẹ naa bii Oloye Bisi Akande, Ọtunba Iyiọla Omiṣore, Ẹnjinia Ṣọla Akinwumi, Ọmọọba Dọtun Babayẹmi, Họn. Famurewa ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Lẹta rẹ niyii: 


No comments:

Post a Comment