IROYIN YAJOYAJO

Monday, 27 July 2026

Gomina Ademọla Adeleke kede ọlude fun awọn oṣiṣẹ ijọba


Lati le fun awọn oṣiṣẹ ijọba laaye lati gba kaadi idibo alalopẹ wọn, Gomina Ademọla Adeleke ti kede pe ki wọn gbọlude lọjọ Tusidee, ọjọ Kejidinlọgbọn, oṣu Keje, ọdun yii.


Awọn oṣiṣẹ ijọba ti ọrọ ọhun kan ni awọn to n ṣiṣẹ nijọba ibilẹ, awọn to n ṣiṣẹ nileewe giga ati bẹẹ bẹẹ lọ.


Ninu atẹjade kan ti olori awọn oṣiṣẹ ijọba l'Ọṣun, Alagba Ayanlẹyẹ Aina, fi sita lo ti ni gomina mọ agbara ti kaadi idibo ni, idi niyẹn tijọba si fi faaye silẹ fun wọn lati gba a ki wọn le raaye ṣojuṣe wọn ninu idibo to n bọ yii.


O rọ awọn oṣiṣẹ eleto ilera atawọn oṣiṣẹ to n pese aabo lati ri i pe wọn ṣiṣẹ papọ laarin ara wọn ki ọlude ọjọ kan yii ma baa ni ipa buburu lori awọn araalu.

No comments:

Post a Comment