Ni imurasilẹ fun idibo gomina ipinlẹ Ọṣun ti yoo waye lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026, awọn ẹgbẹ oṣelu to lorukọ labẹ 'The Democrats' ti ṣabẹwo si ọfiisi ajọ eleto idibo INEC ati ọfiisi Kọmiṣanna funleeṣẹ ọlọpaa.
Wọn sọ pe ẹka mejeeji yii ti ṣe ohun iwuri lọkanojọkan fun aṣeyọri idibo to n bọ lọna naa, o si han ninu iwa ati iṣe wọn pe wọn ṣetan fun eto idibo to gbohunjẹ fẹgbẹ gba awo bọ.
Nigba to n sọrọ lorukọ awọn agbarijopọ ẹgbẹ oṣelu naa, alaga ẹgbẹ Labour, Mustapha Adebayọ Muideen, sọ lọdọ ajọ INEC pe pataki abẹwo ọhun ni lati mọ ibi ti ajọ naa ba iṣẹ de.
O ni, gẹgẹ bii ọkan gboogi lara awọn ti ọrọ idibo naa kan, ti wọn si jẹ alagata laarin awọn ajọ INEC atawọn oludibo, wọn nilo lati maa mọ bi nnkan ṣe n lọ si loorekoore.
Nigba ti wọn de ọfiisi Kọmiṣanna funleeṣẹ ọlọpaa l'Ọṣun, agbẹnusọ wọn, to jẹ igbakeji akọwe ẹgbẹ APC, Waheed Adediran, sọ pe ọkan awọn ẹgbẹ oṣelu ko balẹ latari wahala to n ṣẹlẹ lojoojumọ l'Ọṣun bayii.
Adediran sọ pe awọn nilo idaniloju lati ọdọ awọn ọlọpaa pe aabo to peye wa fun ẹmi ati dukia awọn araalu; ṣaaju, lasiko ati lẹyin idibo ọhun.
Ninu idahun wọn, awọn ti wọn ṣojuu Kọmiṣanna ọlọpaa nibi abẹwo naa fi da awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣelu ọhun loju pe digbi lawọn wa lati ri i pe idibo naa lọ nirọwọrọsẹ.
Lara awọn ẹgbẹ oṣelu to wa nibẹ ni Democratic Leadership Alliance, National Rescue Movement, African Democratic Party, Labour Party, APGA, Social Democratic Party.
Awọn yooku ni Action Alliance, Allied Peoples Movements, Action Alliance Congress, Zenith Labour Party, All Progressives Congress, National Democratic Party, Nigeria Democratic Congress atawọn miran.

No comments:
Post a Comment