Ọkan lara awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress niluu Oṣogbo, Ẹnjinia Kehinde Raji, ti sọ pe oun loun fi owo ara oun pese ina mọnamọna fun awọn eeyan agboole ti akọwe funjọba ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Teslim Igbalaye, ti wa.
Ọmọbibi ilu Oṣogbo ni Raji ati Igbalaye toun naa jẹ aṣaaju ẹgbẹ Accord niluu naa.
Lasiko ti Raji n ṣepolongo ibo ojule-de-ojule fun oludije funpo gomina ninu ẹgbẹ APC, Alhaji Bọla Oyebamiji, lọjọ Tọsidee ọsẹ yii, lo sọrọ naa.
O ni ijọba amunisin niṣejọba ẹgbẹ Accord, ẹnu lasan si ni gbogbo iṣẹ idagbasoke ti wọn sọ pe awọn ṣe niluu Oṣogbo, nitori naa, ki awọn eeyan ilu Oṣogbo gbaruku ti Oyebamiji lati di gomina.
O ni, 'Ẹ ba wa ba awọn eeyan to ku sọrọ, awọn ti a ba nilo lati bẹ, a maa bẹ wọn, a ko ba ẹnikẹni ṣọta, a ko si ba ẹnikẹni ja, iṣẹ ti onikaluku ba ṣe la maa sọ. Mi o gbowo ijọba, mi o gbapo lọwọ ijọba, ẹrọ amunawa ti wọn n lo ni ward 7, 8, 9 ati ward 10, emi ti mo gbe e sibẹ niyii.
''Ina ti wọn n lo lagboole Bọda Muniru, lagboole awọn Bọda Tẹsi, pẹlu ti awọn Aleṣe, awa la ṣe e sibẹ o.Omi to wa ni Arẹsa, awa la ṣe e sibẹ o, omi to wa l'Ayepe, awa la ṣe e sibẹ o, omi to wa ni Better Life, awa la ṣe e sibẹ o, oogun-oju mi ni mo fi ṣe e tori pe mo fẹran awọn eeyan mi, mi o nii jẹ ki iya jẹ yin.
Nitori naa, ti ẹ ko ba fẹ ki iya yẹn tun tẹ siwaju, ẹ jẹ ka ṣe ti AMBỌ taara. Ibo wa ni ka fi sọrọ, ẹ jẹ ka gbaruku ti AMBỌ tori ijọba amunisin nijọba awọn araabi. Wọn ti fẹẹ gba gbogbo ilẹ wa tan, awa ki i sii ṣe ọmọ-ale ilu Oṣogbo.''

No comments:
Post a Comment