IROYIN YAJOYAJO

Sunday, 23 August 2026

Oṣere tiata ilẹ wa nni, Taiwo Hassan, ti jade laye o


Lẹyin ọpọ oṣu to fi jijakadi pẹlu aisan kansa, ọkunrin gbajugbaja oṣere tiata ilẹ wa nni, Taiwo Hassan, ti jade laye.


Ọmọbibi ilu Ilaro nipinlẹ Ogun ni Taiwo Hassan, ẹni ti gbogbo aye mọ si Ogogo, o si lo ọdun mẹrindinlaadọrin loke eepẹ kọlọjọ to de.


Ipele kẹrin aisan kansa lọkunrin yii n koju ti ọkan lara awọn ọmọ rẹ fi ke gbajare pe ọrọ naa ti kọja agbara awọn dokita.


Amọ nirọlẹ ọjọ Aiku ni ọmọ rẹ, Kira, kede pe baba oun ti jade laye.

No comments:

Post a Comment