Alakoso Agba fun igbimọ to ṣepolongo ibo fun gomina ana l'Ọṣun, Alhaja Gboyega Oyetọla, lọdun 2022, Hon. Isreal Ajibọla Famurewa, ti sọ pe iwa aikonimọra ati anikanjọpọn Oyetọla lo fa a ti ẹgbẹ APC fi lulẹ ninu idibo gomina to waye lọjọ Satide to kọja.
O ni awijare lasan ni ki ẹnikẹni maa sọ pe Sẹnetọ Iyiọla Omiṣore lo fa a ti awọn fi jabọ. O ni gbogbo agbegbe ti awọn alagbara ninu ẹgbẹ naa ti wa ni Gomina Ademọla Adeleke ti lu wọn lalubami.
Nigba to n sọrọ lori tẹlifisan kan laipẹ yii ni Famurewa ti sọ pe oun to ṣokunfa ijakulẹ awọn lọdun 2022 naa lo tun fa ti 2026. O ni awọn perete kan ti wọn ṣu mọ Oyetọla nikan ni wọn n pin ipo laarin ara wọn, ti wọn si pa awọn ọmọ ẹgbẹ to ku ti.
Gẹgẹ bo ṣe wi, "Ninu idije bii eleyii, ẹnikan maa jawe olubori, ẹnikan maa lulẹ, kudiẹkudiẹ inu ẹgbẹ wa lo fun Adeleke lanfaani lati jawe olubori yatọ si pe o jẹ gomina ti ọpọlọpọ awọn araalu fẹran latari awọn aṣeyọri rẹ lọfiisi, awọn aṣiṣẹ wa fun un lanfaani lati rọwọ mu lai ṣe wahala.
"Ai nigbagbọ ninu awọn adari wa ni ọpakutẹlẹ ọpọlọpọ wahala ti a doju kọ ninu ẹgbẹ wa, awọn ọmọ ẹgbẹ ko gbagbọ ninu awọn asaaju wa mọ, a nilo adari miran, ki i ṣe adari to maa maa ṣa awọn to fẹẹ ba ṣiṣẹ, a nilo adari ti yoo ko gbogbo ọmọ ẹgbẹ mọra.
"Fun apẹrẹ, ẹ wo awọn ipo ijọba apapọ ti wọn n gbe wa si Ọṣun, oju kan naa ni wọn ti n pin in laarin ara wọn, ipo bii mejidinlọgbọn ni awọn ti adari wa, Alhaji Gboyega Oyetọl, ko rọra, pin mọ ara wọn lọwọ, nigba ti awọn yooku ninu ẹgbẹ kawọ gbera. Iru nnkan bayii ko le mu ki iṣọkan wa ninu ẹgbẹ.
"Iru nnkan yii naa lo ṣokunfa ijakulẹ wa ninu idibo ọdun 2022, nigba ti adari ba mu eeyan bii mẹta pere mọra, awọn yẹn ni wọn jẹ abẹnugan ninu ẹgbẹ, wọn n ṣe bii ọba lori awọn to ku, o di dandan kawọn yooku sọrọ. A sọrọ sọrọ, sibẹ, awọn yii kan naa ni wọn n koraa wọn jọ, wọn gba gbogbo ipo ijọba apapọ, wọn gba oludije fun ipo Sẹnetọ mẹtẹẹta, ipo ile igbimọ aṣofin apapọ mẹsan, ipo ile igbimọ aṣofin ipinlẹ mẹrindinlọgbọn ati bẹẹ bẹẹ lọ. Ki ni wọn fẹ ki awọn yooku maa ṣe?
"Ti ẹ ba n sọ nipa Sẹnetọ Iyiọla Omiṣore, Ifẹ ni Sẹnetọ Omiṣore ti wa, ṣugbọn a lulẹ ni Ila, Ifẹdayọ, Boluwaduro, ṣe a tun fẹẹ sọ pe Omiṣore lo fa iyẹn? Ni gbogbo aaringbungbun Ọṣun nibi ti a ti ni ijọba ibilẹ mẹwaa, ti olori wa tun wa latibẹ, ijọba ibilẹ mẹta pere la ti rọwọ mu. Ni Iwọ-Oorun ti oludije ẹgbẹ wa ti wa, ijọba ibilẹ meje la ti lulẹ, ni Ila-Oorun nibi ti Omiṣore ti wa, ijọba ibilẹ marun la ri mu ninu mẹwaa.
"Mi o gbagbọ pe Sẹnetọ Iyiọla Omiṣore ṣiṣẹ tako ẹgbẹ wa. Lọdọ temi, lati yuniiti idibo lọ titi de ijọba ibilẹ la ti rọwọ mu.
Ohun ti mo n sọ ni pe wahala wa ninu ẹgbẹ wa, ọpọ ọmọ ẹgbẹ ni ko nigbagbọ ninu awọn aṣaaju wa mọ. Ẹ jẹ ka ni adari ti yoo ṣetan kati gbọ aroye gbogbo ọmọ ẹgbẹ, ti yoo si ṣakoso alakoyawọ. A nilo atunto ẹgbẹ APC nipinlẹ Ọṣun ti a ba fẹẹ jawe olubori ninu awọn ibo ọjọọwaju.
"Bakan naa, latibẹrẹ, a mọ pe ilu bii Ẹdẹ ni gomina to wa lori aleefa to tun n dupo ti wa, ṣe lo yẹ ka mu oludije lati agbegbe ti a ti le ri obitibiti ibo lati koju eyi ti wọn ba n gbe bọ lati Ẹdẹ. Eleyii tun da kun ijakulẹ wa, ati pe a ti gbọkan le agbara ijọba apapọ ju."

No comments:
Post a Comment