Ọmọọba Gideon Oyeyẹmi Adebayọ lati ile Arowoẹlẹdẹjoye ni wọn ti kede gẹgẹ bii Olumoro ti ilu Moro nijọba ibilẹ Ariwa Ifẹ.
Ọba Abidoye Oyeniyi waja loṣu keji ọdun yii.
Awọn ọmọọba marun ni wọn fi erongba han lati du ipo naa, ṣugbọn lonii lawọn afọbajẹ ilu naa dibo yan Adebayọ.
Awọn afọbajẹ marun ni wọn dibo, mẹta si dibo fun Ọmọọba Adebayọ nibi eto to waye ninuu sẹkiteriati Ife North West LCDA, Ẹdunabọn.
No comments:
Post a Comment