IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 29 October 2024

Wọnyii ni idi ti ẹgbẹ APC fi ni ki Ọgbẹni Arẹgbẹṣọla lọọ rọọkun nile


Ẹsun mẹfa ọtọọtọ ni awọn ọmọ ẹgbẹ APC nijọba ibilẹ Ila-Oorun Ileṣa fi kan gomina ana, Ọgbẹni Rauf Adesọji Arẹgbẹṣọla. 


Awọn ẹsun naa ni pe o da ẹgbẹ tuntun silẹ ninu ẹgbẹ APC, o pin ẹgbẹ si meji nipa dida igun to pe ni Omoluabi Caucus silẹ, ifidimulẹ eleyii to wa ninu fọnran fidio ipade kan ti wọn ṣe niluu Iwo laipẹ yii, wọn ni o n ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn ẹgbẹ alatako lati yẹpẹrẹ ẹgbẹ APC l'Ọṣun gẹgẹ bo ṣe fidi mulẹ laafin Ataọja lọjọ kẹrin oṣu kinni ọdun 2024.


Bakan naa ni wọn ni o maa n sọrọ aleebu si awọn adari ẹgbẹ naa bii Asiwaju Bola Ahmed Tinubu, Oloye Bisi Akande, Alhaji Gboyega Oyetọla ati bẹẹ bẹẹ lọ, pẹlu bi ko ṣe dibo tabi kopa ninu akitiyan ẹgbẹ naa lati igba idibo apapọ ti ọdun 2019.


Awọn ẹsun naa, gẹgẹ bi akọwe igbimọ to n ṣebawi awọn ọmọ ẹgbẹ naa, Waheed Adediran, ṣe sọ, ni wọn ni o tako abala ikọkanlelogun iwe ofin ẹgbẹ naa. 


Wọn waa fun Arẹgbẹṣọla lanfaani lati dahun si awọn ẹsun yẹn laarin wakati mejidinlaadọta ti lẹta naa ba tẹ ẹ lọwọ.

No comments:

Post a Comment