IROYIN YAJOYAJO

Friday, 25 October 2024

L'Ọṣun, awọn ọlọpaa lu oṣiṣẹ ajọ Sifu Difẹnsi lalubami, wọn tun ti i mọle fọjọ meji


Lati ọjọ Wẹsidee ọsẹ yii ni ọkan lara awọn oṣiṣẹ ajọ Sifu Difẹnsi nipinlẹ Ọṣun ti wa latimọle awọn ọlọpaa lẹyin ti wọn fi lilu da batani si i lara, ọsan ọjọ Furaidee ni wọn si to tu u silẹ. 


Ohun to ṣẹlẹ, gẹgẹ bi Gbagede ṣe gbọ ni pe, ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ ọjọ Tusidee, iyẹn ọjọ kejilelogun oṣu kẹwaa yii, ni awọn kan ti wọn wọ aṣọ ankara wa mọto Sienna niwakuwa wọnuu Elizabeth Estate niluu Oṣogbo. 


Wọn ba awọn oṣiṣẹ Sifu Difẹnsi ti wọn n ṣọ Estate naa lẹnuu geeti, wọn ni ọlọpaa lawọn, wọn si sọ pe ṣe lawọn wa lati fi pampẹ ọba gbe ọdaran kan ninu ibẹ ati pe ipinlẹ Ọyọ lawọn ti wa.  




Awọn Sifu Difẹnsi beere pe ki wọn fi kaadi idanimọ wọn han pe loootọ Ọlọpaa ni wọn, ṣugbọn ẹnikan ti ọrọ naa ṣoju ẹ ṣalaye fun wa pe, ṣe lawọn ọlọpaa yii bẹrẹ sii gboju aagan si awọn Sifu Difẹnsi yii, wọn ni agbara wo ni wọn ni lati beere ami idanimọ wọn. 


Bayii ni wọn binu lọ lọjọ naa, ṣugbọn ipadabọ Abija ni wọn fi ọrọ naa ṣe lọjọ Wẹsidee, awọn bii mẹẹdogun ni wọn wa sibẹ. 


A gbọ pe wọn kọkọ lu Sifu Difẹnsi ti wọn ba lẹnu geeti nla naa lalubami, wọn fa aṣọ rẹ ya, wọn fi ṣekẹṣẹkẹ de e lọwọ, wọn si wọ ọ lọ si agọ ọlọpaa to wa ni Ataọja, latibẹ ni wọn si ti gbe e lọ si olu ileeṣẹ ọlọpaa. 


Atẹjade kan latọdọ agbẹnusọ ajọ Sifu Difẹnsi l'Ọṣun, Kehinde Adeleke, sọ pe gbogbo igbiyanju awọn lọgalọga ajọ naa lati gba ọkunrin yii silẹ lagọ awọn ọlọpaa lo ja si pabo, afigba to lo ọjọ meji lagọọ wọn. 


O ni fọnran fidio to wa nita fi han kedere bi awọn ọlọpaa yii ṣe lu ọmọ ajọ Sifu Difẹnsi, idi si niyẹn tawọn fi n beere fun idajọ ododo lori ọrọ naa nitori olootọ kan ko gbọdọ ku sipo ika. 


Ṣugbọn agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe ọkunrin Sifu Difẹnsi yẹn lo kọkọ lu ọlọpaa meji, ko too di pe awọn ọlọpaa yooku kapaa rẹ. O ni iwadii ṣi n lọ lọwọ lori ọrọ naa.

No comments:

Post a Comment