Ọkan pataki lara awọn oṣere tiata ilẹ wa to dagba julọ nni, Alhaji Abdulsalam Sanyaolu ti gbogbo eeyan mọ si Charles Olumọ, ti ku.
Oṣu keji ọdun 1925 ni wọn bi Oluọmọ ti wọn tun n pe ni Agbako niluu Owode nipinlẹ Ogun.
Ọdun mejidinlaadọrun sẹyin lo bẹrẹ sii kopa ninu fiimu. Ileejọsin The Apostolic Church, Mushin lo ti kọkọ ni iwuri lati maa ṣe ere tiata.
Aarẹ ẹgbẹ TAMPAN lorileede yii, Mr Latin, lo kede iku baba naa lori ikanni ayelujara rẹ pe baba naa jade laye loni ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kẹwaa ọdun 2024.
Ọdun mejilelọgọrun ni baba naa lo loke eepẹ ko too jade laye.
His year was supposed to be 1925 and not 1025. The man was highly talented in the Theatre profession.I learnt that he doesn't usually rehearse before participating in a film, all he needs to know was the role assigned to him. Once he hears "ACTION" he will play that role effectively. The vacuum created may be difficult to fill within the Association!
ReplyDeleteMay his gentle soul rest in perfect peace!