Oṣiṣẹ ajọ Sifu Difẹnsi kan, Mohammed Ọpatọla, lo ti dagbere faye lọjọ Mọnde, ọjọ kẹrin oṣu kọkanla ọdun yii.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ọfiisi ajọ naa to wa niluu Iwo ni Ọpatọla ti n ṣiṣẹ, ọsẹ to kọja lo si ṣe ayẹyẹ ayajọ ọjọ ibi rẹ.
Gbagede gbọ pe lọsẹ diẹ sẹyin ni Ọpatọla gba igbega lẹnu iṣẹ, oun atawọn akẹẹgbẹ rẹ si n reti pe owo igbega yii yoo farahan ninu owo oṣu kẹwaa ti wọn maa gba.
Ṣugbọn lọjọ Mọnde to gba alaati owo-oṣu kẹwaa, ọkan lara awọn akẹẹgbẹ rẹ lọfiisi sọ pe inu rẹ ko dun pe ko si afikun owo igbega yii nibẹ, gbogbo wọn si mẹnu kuro lori rẹ lẹyin ti wọn ṣaroye diẹ.
Lẹyin iṣẹju diẹ lo wọ ile igbọnsẹ lọ, ṣugbọn nigba ti awọn akẹẹgbẹ rẹ ko tete ri i ko jade ni wọn lọ wo o nibẹ, o si ya wọn lẹnu lati ba a nilẹẹlẹ ile igbọnṣẹ.
Wọn gbe e digbadigba lọ si ọsibitu, ṣugbọn ẹpa ko boro mọ, o ti jade laye.
No comments:
Post a Comment