IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 20 May 2025

A ko gbọdọ tẹsiwaju lati ko igbe-aye awọn araalu le onijo lọwọ - Babayẹmi


Oludije funpo gomina ipinlẹ Ọṣun labẹ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Ọmọọba Dọtun Babayẹmi, ti sọ pe ọrọ iṣakoso odidi ipinlẹ kọja eyi ti awọn lamẹẹtọ le yọnda si ọwọ alawada kan lasan, ti ko mọ nnkan miran ju ijo lọ.


O ni atari ajanaku ni iṣẹ gomina ipinlẹ jẹ, ki i ṣe ẹru ẹni ti ko ni imọ kikun nipa bi a ṣee dari awọn eeyan, paapaa awọn ọdọ.


Lasiko to lọ sọdọ awọn adari ẹgbẹ APC nipinlẹ Ọṣun fun ifikunlukun nipa erongba rẹ lati kopa ninu idibo abẹle ẹgbẹ naa, nipasẹ eyi ti wọn yoo ti fa oludije kalẹ ni Babayẹmi ṣalaye pe gbogbo amuyẹ adari to lafojusun rere fun awọn eeyan rẹ loun ni.


O sọ siwaju pe to ba jẹ pe awọn iṣejọba to ti kọja l'Ọṣun lanfaani si ida kan ninu ida mẹta owo to n wọle latọdọ ijọba apapọ bayii, idagbasoke ti ko lẹgbẹ i ba ti ṣẹlẹ.


Amọ, bi owo to n wọle sipinlẹ Ọṣun bayii ṣe pọ to, pẹlu erongba rere ti Aarẹ Tinubu ni fun awọn ọmọ orileede yii, Babayẹmi sọ pe wọn ko lo o daradara, ko si yọ rara, idi si niyẹn ti oun fi jade lati dupo gomina.


O fi kun ọrọ rẹ pe ti wọn ba fẹẹ fi ọrọ 'West lo kan' to mimu oludije, gbogbo awọn to ti jade lati Iwọ-Oorun Ọṣun bayii ni wọn kunju oṣunwọm, ṣugbọn oun le sọ pẹlu irẹlẹ pe oun pegede julọ laarin wọn.


Babayẹmi tẹ siwaju pe oun ti kọkọ gba iyọnda gomina ana, Adegboyega Oyetọla lori erongba oun, oun si tun ti ri awọn adari ẹgbẹ lati mọ nipa ofin to rọ mọ irinajo ti oun fẹẹ gun le.


O ni oun atawọn alatilẹyin oun yoo bẹrẹ si i lọ kaakiri ẹsẹkuuku ati igberiko nipinlẹ Ọṣun lati le jẹ ki wọn mọ nipa oniruuru afojusun ti oun ni fun wọn ṣaaju ibo ọdun 2026.

No comments:

Post a Comment