IROYIN YAJOYAJO

Monday, 19 May 2025

Atunṣe ọkọ akọtami da ariyanjiyan silẹ laarin ọmọọṣẹ Adeleke ati Oyetọla l'Ọṣun


Lati le jẹ ki ọrọ eto aabo munadoko sii nipinlẹ Ọṣun, Gomina Ademọla Adeleke ti kede pe iṣẹ ti fẹẹ pari lori atunṣe awọn ọkọ akọtami mọkanla ninuu mejilelogun ti ijọba Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla ra.


Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ fun gomina, Mallam Ọlawale Rasheed fi sita lo ti ṣalaye pe ṣe ni ijọba Alhaji Gboyega Oyetọla pa awọn ọkọ akọtami ọhun ti lai fọwọ kan wọn fun odidi ọdun mẹrin to lo.

Ṣugbọn agbẹnusọ fun Oyetọla nigba naa, Ismail Omipidan kọ sorii feesibuuku rẹ pe ko si atunṣẹ kankan tijọba Adeleke ṣe lara awọn ọkọ naa ju pe wọn tun wọn kun lọ.

O ni bi wọn ṣe gbe ọda tuntun le ori awọn Ọmọluabi Buses lati fi tan awọn araalu jẹ naa ni wọn tun gbe ọda le ori awọn ọkọ yii lati le sọ pe ṣe lawọn ra wọn lati fi kin awọn ẹṣọ alaabo lọwọ.

Amọ ṣa, Ọlawale ṣalaye pe ara aje lo ta gomina nitori Adeleke jẹ ẹni ti ki i fẹ ki dukia ijọba Ọṣun ṣofo, nigba to si ri i pe awọn ọkọ naa ti n dipẹta, lo ṣe paṣẹ pe ki wọn di titunṣe kiakia.

O ni igbesẹ yii yoo fun awọn oṣiṣẹ alaabo lanfaani lati ṣiṣẹ wọn bii iṣẹ, eto aabo to peye yoo si wa fun ẹmi ati dukia awọn araalu kaakiri ipinlẹ Ọṣun.

No comments:

Post a Comment