Ajọ to n ri si akoso awọn ọgba ẹwọn orileede yio, Nigerian Correctional Services (NCoS) ti kede ẹbun miliọnu naira fun ẹnikẹni to ba gburo awọn ẹlẹwọn ti wọn sa kuro lọgba wọn to wa niluu Ileṣa.
Aago meji idaji ọjọ Tusidee ọsẹ yii la gbọ pe arọọrọda ojo to rọ niluu Ileṣa wo ibudo naa lulẹ, eleyii to si fun awọn ẹlẹwọn meje lanfaani lati da lọ.
Alukoro ajọ naa, Abubakar Umar ṣalaye pe awọn ti n ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn ẹṣọ alaabo to ku atawọn aṣaaju agbegbe ọgba ẹwọn ọhun lati ṣawari awọn to sa lọ yii.
O sọ siwaju pe yatọ si ẹbun owo, aabo wa fun ẹmi ẹni to ba waa ta awọn lolobo lorii bi wọn ṣe le ri wọn mu nitori ko sẹni ti yoo mọ orukọ wọn.
No comments:
Post a Comment