IROYIN YAJOYAJO

Sunday, 18 May 2025

APC ti mu amunbọ l'Ọṣun, alumọlẹ ni Gomina Adeleke maa lu wọn lọdun 2026 - Mallam Ọlawale


Wọn ti fẹsun kan akọwe apapọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress lorileede yii pe awọn iroyin eke lo ku to n gbe kaakiri lati fi ba ijọba ipinlẹ Ọṣun lorukọ jẹ.


Agbẹnusọ fun Gomina Ademọla Adeleke, Mallam Ọlawale Rasheed, ṣalaye pe ko si olukọ tabi awọn oṣiṣẹ eto ilera kankan tijọba Adeleke da duro. O ni nigba to ku ọsẹ diẹ tiṣejọba ana yoo kogba wọle l'Ọṣun ni wọn gba awọn ọmọ ẹgbẹ wọn gẹgẹ bii olukọ ati oṣiṣẹ eto alaabo lati le dabaru iṣejọba tuntun to n bọ lọna nigba naa.


Ọlawale ṣalaye pe awọn tijọba le danu ko figba kankan si lara awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Ọṣun nitori gbigbaa wọn lodi si ofin iṣẹ ijọba.


Ọlawale yannana gbogbo awọn isọri iṣejọba ti Ajibọla sọ lori ifọrọwerọ kan laipẹ yii pe Adeleke ko ti ṣe daadaa, o ni iṣẹ nlọ lọwọ lorii afara abẹyẹfo to wa ni Okefia, bẹẹ ni iṣẹ ko duro lori ipese omi ẹrọ to mọ gaara ati rira katakata mọkanlelọgbọn fun imugbooro iṣẹ agbẹ kaakiri ipinlẹ Ọṣun.


O ni ko si bi Ajibọla ṣe fẹẹ parọ pe ijọba Adeleke ko san owo oṣu ati ajẹmọnu awọn oṣiṣẹ deedee, tabi pe iṣẹ duro lorii titun papa iṣere nla ilu Oṣogbo to ti wa ṣe, ati fifi orukọ awọn oṣiṣẹfẹyinti ẹgbẹrun lọna ọgbọn silẹ fun eto ilera adojutofo.


O ni Ajibọla ko gbọdọ ro pe ẹnikẹni bu ẹnu atẹ lu u pẹlu bi awọn ọmọlẹyin AMBỌ toun naa jẹ oludije funpo gomina labẹ ẹgbẹ APC Ọṣun ṣe ja a si kolobo, ṣe lawọn kan n kaanu rẹ.


Ọlawale ni oun n fi asiko yii sọ fun Ajibọla pe, ati 'Amunbọ' o tabi 'Alumọnlẹ' to jẹ ti Alubarika funraarẹ, ko si eyi to le da awọn araalu duro lati dibo wọn lẹkunrẹrẹ fun Adeleke lọdun 2026.

No comments:

Post a Comment