IROYIN YAJOYAJO

Friday, 23 May 2025

Oju ifa ti la, ṣe ni ẹnu ifa to ba fi talaka jọba maa gbẹ - Ọọni Ifẹ


Ọọni Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi ti sọ pe oju ifa ti wọn fi n mu ọba ti la bayii, ẹni to jẹ gbajumọ lo ku ti ifa n mu si ipo ọba.


Nibi awẹjẹwẹmu ti wọn ṣe fun ayẹyẹ igbopa-aṣẹ Ọwa Obokun Adimula ilẹ Ijeṣa, Ọba Clement Adesuyi Haastrup, Ajimọkọ Kẹta, to waye lọjọ Furaidee ọsẹ yii ni Ọọni ti sọrọ ọhun.


Ọba Adeyẹye ṣalaye pe inu oun dun pe Ọlọrun lo Gomina Ademọla Adeleke lati yan ọba to dara fun awọn Ijeṣa.


O ni ifa gomina laju daadaa, o si fi eeyan nla jọba. O ki awọn ọmọbibi ilẹ Ijeṣa ku oriire ayẹyẹ ọba tuntun naa, o si rọ kabiesi lati sọ ara rẹ di aatan to n gba ẹgbin mọra.

No comments:

Post a Comment