IROYIN YAJOYAJO

Saturday, 24 May 2025

Nitori ọdun Ileya, Adeleke ṣofin tuntun fun awọn eeyan Ifọn, Ilobu ati Ẹrin Ọṣun


Gomina ipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke ti paṣẹ pe ki ayipada ba akokoo isede to n lọ lọwọ ninu ilu Ifọn, Ilobu ati Ẹrin Ọṣun.


Ninu atẹjade kan ti kọmiṣanna fun ọrọ iroyin ati ilanilọyẹ, Oluọmọ Kọlapọ Alimi fi sita ni gomina ti sọ pe dipo aago mẹfa alẹ si mẹfa aarọ ti isede naa fi n waye tẹlẹ, o ti di aago mẹsan alẹ si aago marun idaji bayii.


Adeleke ṣalaye pe iyatọ ti n wa lagbegbe naa pẹluu bi wọn ṣe n gba alaafia laaye laarin ara wọn.


O ṣekilọ fun awọn ọba agbegbe mẹtẹẹta lati ṣekapa awọn araalu wọn, nitori ọba ti wọn ba tun gburo wahala lagbegbe rẹ yoo foju winna ofin.


Bakan naa lo ni ki awọn ẹṣọ alaabo ṣi wa ninu ilu mẹtẹẹta ni gbogbo wakati lati ri i daju pe ogun to ti ṣẹ ko gberi mọ.


Adeleke ki awọn eeyan ilu Ifọn, Ilobu ati Ẹrin-Ọṣun ku imura ọdun Ileya to n bọ lọna.

No comments:

Post a Comment