IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 14 May 2025

Wahala nbọ o! Awọn aṣofin ti fẹẹ yọ Alaafin nipoo alaga igbimọ lọbalọba ipinlẹ Ọyọ


Awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin marun-un nipinlẹ Ọyọ ti gbe abadofin kan lọ siwaju ile ninu eyi ti wọn ti ni ki ipo alaga igbimọ lọbalọba ipinlẹ naa wa laarin Alaafin, Olubadan ati Sọun Ogbomọsọ.


Tẹ o ba gbagbe, ọdun 2011 ni gomina ipinlẹ naa nigba yẹn, Ọtunba Alao Akala ti kọkọ gbe iru igbesẹ bẹẹ ko too di pe awọn lọbalọba nibẹ fariga pe ko le ṣe e ṣe.


Amọ ni bayii, Gbagede gbọ pe aba ọhun, eleyii ti abẹnugan ile, Adebọ Ogundoyin wa lara awọn ti wọn gbe e lọ, fẹ ko jẹ pe Olubadan le dari ipade lọbalọba ti Alaafin ko ba ti raaye lọ, Sọun si le dari ti Alaafin ati Olubadan ko ba si nibẹ.

No comments:

Post a Comment