IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 14 May 2025

Ọṣun: Ajumọṣe gbogbo awa ẹgbẹ oṣelu ni aṣeyoṛi ibo ọdun 2026 - Ọdẹyẹmi


Ẹgbẹ oṣelu New Nigeria Peoples Party (NNPP) nipinlẹ Ọṣun ti ke si gbogbo awọn ẹgbẹ oṣelu to ku lati ṣiṣẹ papọ pẹlu erongba gbigba iṣakoso ipinlẹ Ọṣun kuro lọwọ ẹgbẹ oṣelu PDP lọdun 2026.


Ninu atẹjade kan ti alaga ẹgbẹ naa, Dokita Tosin Ọdẹyẹmi, fi sita lo ti ni iṣẹ ajumọṣe nikan lo le mu erongba naa rọrun nitori ko si ẹgbẹ oṣelu kanṣoṣo tabi oludije kanṣoṣo to le da a ṣe.


O ni idibo gomina ọdun 2026 jẹ eyi to ṣe pataki pupọ nipinlẹ Ọṣun, gbogbo ẹgbẹ oṣelu si gbọdọ mura lati gba ipinlẹ Ọṣun.


Ọdẹyẹmi ṣalaye pe ẹgbẹ NNPP ti ṣẹtan lati ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn ẹgbẹ oṣelu lati gbe oludije ti yoo ṣe itẹwọgba kalẹ, ti gbogbo araalu yoo si ṣiṣẹ fun.


O ni iwadii ti fi han bayii pe oludije to ba ṣetẹwọgba yoo kojuu Adeleke, yoo si jawe olubori, koda, yoo ri ibo ida ogoji ninu ida ọgọrun to jẹ ti awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP.


Gẹgẹ bo ṣe wi, 'Afojusun kan ṣoṣo ti a ni bayii ni lati gbajọba lọwọ ẹgbẹ PDP ti wọn kun fun ẹtan yii. Gbogbo awa ẹgbẹ oṣelu gbọdọ ṣiṣẹ papọ fun aṣeyọri ibo ọdun 2026 nipinlẹ Ọṣun'

No comments:

Post a Comment