IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 4 June 2025

2026: Ẹmi awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun dọwọ rẹ, ko gbọdọ si itajẹsilẹ o - Igbimọ Agba kilọ fun Adeleke


Igbimọ Agba Ọṣun labẹ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress ti kilọ fun Gomina Ademọla Adeleke lati ri i pe aabo to peye wa fun ẹmi ati dukia awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun lasiko idibo gomina ti yoo waye lọjọ kẹjọ oṣu kẹjọ ọdun 2026.


Nibi ipade oloṣooṣu wọn to waye lọjọọ Tusidee ọsẹ yii nilee Alhaji Gbadebọ Ajao, ni awọn agbaagba naa ti sọ pe eto oṣelu ko gbọdọ mu itajẹsilẹ dani rara.


Wọn ni gbogbo araalu ni wọn gbọdọ lanfaani lati dibo fun ẹnikẹni tabi ẹgbẹ oṣelu to ba wu wọn lai ṣe pe ijọba to wa lode fagidi mu wọn tabi dunkoko mọ wọn.


Nibi ipade ọhun, eyi ti alaga wọn, Ẹnjinia Sọla Akinwumi, dari ni wọn ti ṣeleri atilẹyin wọn fun awọn adari ẹgbẹ APC l'Ọṣun, bẹẹ si ni ki gbogbo ọmọ ẹgbẹ tẹ siwaju ninu awọn igbesẹ to le mu ẹgbẹ naa ṣaṣeyọri ninu idibo ọdun to n bọ ọhun.


Igbimọ Agba rọ awọn adari ẹgbẹ lati maa ṣepade loorekoore pẹlu awọn oludije, ki wọn si jẹ ki wọn mọ pataki iṣọkan ati idi ti wọn fi gbọdọ yẹra fun ọrọ alufansa sisọ eleyii to le da iyapa silẹ ninu ẹgbẹ.


Wọn ki gbogbo awọn olugbe ipinlẹ Ọṣun ku imura ọdun Ileya.

No comments:

Post a Comment