Olowu ilu Kuta nipinlẹ Ọṣun, Ọba Adekunle Oyelude Makama, Tẹgbosun Kẹta, ti sọ pe ohun kan ṣoṣo ti gbogbo ẹni to ba fẹran iran Yoruba gbọdọ maa fọnrere bayii ni ibaṣepọ to dan mọran laarin Ọọni Ifẹ ati Alaafin ilu Ọyọ.
Ọba Makama sọrọ yii lasiko to n gbalejo Alaafin ilu Ọyọ, Ọba Abimbọla Akeem Ọwọade, laafin rẹ lọjọọ Tusidee ọsẹ yii.
O ṣalaye pe ṣe lawọn eeyan apa Ariwa orileede yii maa n gbe Sultan ti Ṣokoto, Muhammadu Saad Abubakar ati Shehu ti Bornu gẹgẹgẹ, ti wọn si maa n bu ọla fun wọn, eleyii ti ko ri bẹẹ nilẹ Yoruba latari aisi iṣọkan.
Olowu sọ siwaju pe, 'Asiko to tọ lẹ jọba. A gbọdọ wa iṣọkan ri laarin awa ọba ilẹ Yoruba. Ọlọrun ti fi ẹyin ati Ọọni ṣe olori ni ilẹ Yoruba. Fun idagbasoke iran Yoruba, ibaṣepọ to gun rege gbọdọ wa laarin ẹyin mejeeji. Iku Baba Yeye, abẹwo ti ẹ n ṣe yii ni itumọ to lagbara. Wahala wa ni ilẹ Yoruba, ṣugbọn Ọlọrun ti sọ pe asiko ti to fun wa lati parapọ ṣọkan.
'Iṣọkan ilẹ Yoruba pọn dandan bayii o, ẹ ko le gbọ ija laarin Sultan Sokoto ati Shehu Borno, koda bi wọn ni ede aiyede, ko le jade sita. Ọmọ wa, Bọla Tinubu ni aarẹ orileede Naijiria bayii, a gbọdọ ṣugbaa rẹ lati ṣaṣeyọri'
Nigba to n sọrọ, Alaafin Ọwọade dupẹ lọwọọ Ọba Makama, o ni lati ọdun meji sẹyin loun ti n kiyesi gbogbo igbelarugẹ ti Olowu Kuta n ṣe fun aṣa ati iṣe Yoruba ni gbogbo igba lori ikanni ayelujara.
O ni inu oun dun fun awọn ọrọ iyanju ti Ọba Makama fun oun yii, o si tun fi idi rẹ mulẹ pe isọkan ṣe pataki ni ilẹ Yoruba.
No comments:
Post a Comment