IROYIN YAJOYAJO

Monday, 2 June 2025

GSI: Awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun ti sọrọ soke, ki ẹgbẹ APC lọọ gbe jẹẹ fori - Sunday Bisi


Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party ti gboṣuba fun abọ iwadii ti ajọ kan to n tọpinpin eto idibo, Geopolitical Survey International, GSI, ṣe lori idibo gomina ti yoo waye lọjọ kẹjọ oṣu kẹjọ ọdun 2026 nipinlẹ Ọṣun.


Ninu atẹjade kan ti alaga wọn nipinlẹ Ọṣun, Hon. Sunday Bisi, fi sita lo ti ṣalaye pe abajade iwadii naa fi han kedere pe ololufẹ awọn araalu ni Gomina Ademọla Adeleke ati pe ẹgbẹ PDP ti reekan walẹ kaakiri kọrọkọndu ipinlẹ naa.


Ẹgbẹ PDP ṣalaye pe bi iwadii naa ṣe sọ pe eeyan ida marunlelọgọta ninu ọgọrun lo ti pinnu lati dibo fun ẹgbẹ PDP, nigba ti eeyan ida mẹrindinlaadọrin ninu ida ọgọrun gba lati dibp fun Gomina Adeleke, fi han pe digbi lawọn araalu wa lẹyin iṣejọba to wa lode yii.


Wọn ni 'Abọ iwadii naa kọja ọrọ iye nnkan, awọn araalu ni wọn sọrọ soke nipa itẹlọrun, igbẹkẹle ati ireti ti wọn ni ninuu gomina to mu igbayegbadun wọn lọkunkundun.


'O fi han pe ẹgbẹ wa n gbilẹ sii lojoojumọ. A mọ pe akọsìlẹ yii yoo maa gbẹnusoke sii lojoojumọ, ko si too di oṣu kẹjọ ọdun 2026, a ti maa ni ida aadọrin ninu ọgọrun.


'Awọn eeyan Ọṣun ti sọ tipẹtipẹ nipa atilẹyin wọn fun iṣejọba ẹgbẹ wa, gbogbo wọn ni wọn si fẹran Gomina Adeleke nitori onirẹlẹ ati adari to ni imọlara ohun ti awọn araalu n doju kọ ni'


Hon. Bisi sọ pe awọn ti bẹrẹ sii lọ kaakiri awọn ẹsẹkuuku lati tubọ maa la awọn eeyan lọyẹ nipa iforukọsilẹ fun eto idibo ati lati rii daju pe idibo to n bọ ọhun kẹsẹjari.


Ẹgbẹ PDP waa ke si ẹgbẹ oṣelu APC lati gbe jẹẹ fori, ki wọn si tete mọ pe gbọn-in-gbọn-in lawọn araalu wa lẹyin iṣejọba Gomina Adeleke.

No comments:

Post a Comment