IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 5 June 2025

Ẹ lọọ kọ iwa ọmọluabi, Aarẹ Tinubu ki i ṣe ẹni arifin o - PDP Ọṣun kilọ fẹgbẹ APC


Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) nipinlẹ Ọṣun ti kilọ fun awọn ọmọ ẹgbẹ All Progressives Congress lati dẹkun sisọ ọrọ alufansa si Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu lorii bo ṣe gba Gomina Ademọla Adeleke lalejo laipẹ yii.


Ninu atẹjade kan ti alaga ẹgbẹ naa, Hon. Sunday Bisi, fọwọ si lo ti ṣapejuwe iwa ti awọn ọmọ ẹgbẹ APC hu ọhun bii idojuti, to si fi wọn han gẹgẹ bii ẹni ti ko ni oye iṣejọba ati ibaṣepọ laarin ẹgbẹ oṣelu labẹ iṣejọba tiwantiwa.


Bisi sọ siwaju pe bi wọn ṣe n sọrọ laulau si Aarẹ Tinubu latigba ti fọto abẹwo naa ti bọ sita fi han pe ko si iwa ọmọluabi kankan lara wọn, bẹẹ ni wọn ko bọwọ fun agba.


O ni ṣe ni ki wọn tete gba kamu nitori gbogbo igba ni Gomina Adeleke yoo maa lo anfaani to ba ni, to fi mọ biba aarẹ fọrọjomitooro ọrọ, lori ohun to ba le mu idagbasoke ba ipinlẹ Ọṣun.


Sunday Bisi fi kun ọrọ rẹ pe ki i ṣe igba akọkọ niyii tawọn ọmọ ẹgbẹ APC yoo huwa alailẹkọ naa, o ni bi wọn ṣe ṣe nigba ti awọn bii iyawo aarẹ, Olurẹmi Tinubu, Ado Doguwa ati Fẹmi Gbajabiamila wa sipinlẹ Ọṣun naa niyẹn.


O ran wọn leti pe ọjọ mẹta ọtọọtọ ni gomina Ọṣun nigba kan, Oloye Bisi Akande fi gbalejo aarẹ igba naa, Oluṣẹgun Ọbasanjọ nigba to waa ṣiṣọ lori awọn iṣẹ akanṣe pẹlu ijiroro to le ṣe ipinlẹ lanfaani.


Alaga yii gba awọn ọmọ ẹgbẹ APC nimọran lati lọọ kọ iwa ọmọluabi lọdọ awọn bii Baba Bisi Akande nipa itumọ ipo adari, ki wọn si fi iwa inarobo silẹ.

No comments:

Post a Comment