IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 5 June 2025

Irin afaralokun lẹ rin lọ sile aarẹ, baalu to ti gbera lẹ n ṣẹwọ si - APC Ọṣun yọ ṣuuti ete si idile Adeleke


Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, nipinlẹ Ọṣun ti sọ pe bii omi ti wọn da si ẹyin lara ni abẹwo ti Gomina Ademọla Adeleke, ẹgbọn rẹ ati Davido ṣe sọdọ Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu niluu Eko laipẹ yii, ko ni ipa kankan lori ọrọ oludije funpo gomina ninu ẹgbẹ APC Ọṣun.


Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ẹgbẹ APC, Mọgaji Kọla Ọlabisi fi sita ni wọn ti sọ pe gbogbo aye lo mọ Aarẹ Tinubu gẹgẹ bii ọga-ọga to ba di ọrọ oṣelu, idi niyẹn ti ko fi yẹ ki ẹnikẹni ri ọrọ irin idile Adeleke ọhun ro rara.


Gẹgẹ bi atẹjade naa ṣe wi 'A ko gbọdọ gbagbe pe aarẹ gbogbo orileede yii ni Tinubu lai fi ti ẹgbẹ oṣelu, ẹsin tabi ẹya ṣe, ko si si ẹni ti ko le ṣabẹwo sọdọ aarẹ niwọn igba ti abẹwo rẹ ko ba ti nii mu ipalara ba aarẹ.


'Digbi ni ẹgbẹ wa wa nipinlẹ Ọṣun, a si le fi gbogbo ẹnu sọ ọ pe a ni awọn to kajuẹ gẹgẹ bii oludije, ti wọn si ti n lọ kaakiri bayii lati fi erongba wọn han lori idibo ọdun 2026 lojuna a ti gba ijọba lọwọ ṣubuṣeree gomina ti a ni bayii.


'Ẹni to ba woye oju awọn mẹtẹẹta ti wọn lọ sọdọ aarẹ yoo mọ pe bi wọn ko ba le nnkan, nnkan kan n le wọn. Gomina Adeleke, ẹgbọn rẹ ati Davido nikan ni wọn mọ ibi ti bata ti n ta wọn lẹsẹ, ina si ti bọ lu ẹgbẹ PDP Ọṣun laṣọ.


'Lootọ ko si ohun to buru ninuu ki gomina ṣabẹwo sọdọ aarẹ orileede, ṣugbọn nibi, a n sọrọ nipa gomina ti ko fi ikorira rẹ si aarẹ pamọ latẹyinwa, ti ko si figba kankan ba aarẹ fọwọsowọpọ lori eto ọrọ-aje ri gẹgẹ bi awọn gomina yooku ṣe n ṣe.


'Ko si ikanni ayelujara ti oun atawọn ẹnuujawaya oniroyin rẹ ko lo lati fi ẹnu ṣaata aarẹ atijọba rẹ, bẹẹ ni ko si akọsilẹ ibi ti Adeleke ti parọwa sawọn araalu lati farada oniruuru eto tijọba n ṣe bayii.


'Dipo eyi, ipolongo ọtẹ ni wọn n ṣe kaakiri nipa Aarẹ Tinubu atawọn minisita rẹ ti wọn n fojoojumọ ṣiṣẹ takuntakun fun idagbasoke orileede yii.


'Fọnran fidio ibi ti awọn akẹkọọ Ọba Laoye Grammar School, nijọba ibilẹ Guusu Ẹdẹ, ti wọn bẹ lọwẹ lati maa pariwo 'ole' le Aarẹ Tinubu lori wa kaakiri ayelujara.


'A dupẹ lọwọ Aarẹ Bọla Tinubu fun gbigba awọn Adeleke lalejo lasiko irin afaralokun ọhun. Yoo wa ninu akọsilẹ pe nigba ti awọn araalu ba fibinu fi ibo wọn taari Adeleke danu lọdun 2026, ko nii ri ọrọ aarẹ mu mọnu nitori baalu to ti gbera ni wọn n ṣẹwọ si'

No comments:

Post a Comment