IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 4 June 2025

OSUN 2026: Ọjọgbọn Durodoye darapọ mọ awọn oludije, o ni oun fẹẹ sọ ipinlẹ Ọṣun di apewaawo


Ọjọgbọn pataki kan ninu imọ iṣiro, Rafiu Durodoye, ti fi erongba rẹ han bayii lati dije fun ipo gomina ipinlẹ Ọṣun ninu idibo ti yoo waye lọjọ kẹjọ oṣu kẹjọ ọdun 2026.


Durodoye, ọmọbibi agboole Iyalode niluu Oṣogbo ṣeleri pe ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress ba le gba oun laaye nipasẹ fifun oun ni tikẹẹti ẹgbẹ gẹgẹ bii oludije, ipinlẹ Ọṣun yoo di apewaawo kaakiri orileede Naijiria.


Lasiko to lọ sọdọ awọn adari ẹgbẹ naa ni sẹkiteriati wọn niluu Oṣogbo lati sọ nipa erongba rẹ, Ọjọgbọn Durodoye sọ pe ọpọlọpọ iriri ati ọgbọn-inu teeyan fi maa n mu ayipada rere ba awujọ loun ti ni, oun si ṣetan lati lo wọn fun idagbasoke ipinlẹ Ọṣun.


Gẹgẹ bo ṣe wi, nnkan ibanujẹ ni bi ọpọlọpọ ọdọ ṣe n fẹsẹ gbalẹ kaakiri ilu bayii lai si iṣẹ ti wọn le ṣe, o ni ijọba oun yoo mu ọrọ awọn ọdọ yii lọkunkundun, awọn naa yoo si le fọwọ sọya fun ọjọ ọla to dara.


Lori eto ẹkọ, o ni iwadii fi han bayii pe awọn ileewe perete to jẹ tijọba ipinlẹ Ọṣun ni wọn ni yaara ikawe, iyẹn Library, ara awọn igbesẹ ti oun yoo si kọkọ gbe gẹgẹ bii gomina niyẹn nitori yaara ikawe pọn dandan ni gbogbo ileewe.


Ọjọgbọn Durodoye sọ siwaju pe ko si ẹka ti oun ko nii nawọ iṣẹ de, oun si kaju ẹ ti ẹgbẹ ba gba oun laaye.


Nigba to n fesi, alaga ẹgbẹ oṣelu APC l'Ọṣun, Sooko Tajudeen Lawal, sọ pe inu oun dun fun irufẹ awọn to n fi ifẹ han lati dije ninu ẹgbẹ naa nitori gbogbo wọn ni wọn kunju osunwọn, ti wọn si ni gbogbo amuyẹ to tọ.


O ke si gbogbo wọn lati wa niṣọkan, ki wọn mọ pe afojusun kansoso tawọn ni ni lati pada sile ijọba lọdun to n bọ.

No comments:

Post a Comment