IROYIN YAJOYAJO

Monday, 2 June 2025

Iwa ọdaju ni bijọba apapọ ṣe gbẹsẹ le owo to yẹ ko wa sijọba ibilẹ wa - Alimi



Kọmiṣanna fun eto iroyin ati ilanilọye nipinlẹ Ọṣun, Oluọmọ Kọlapọ Alimi, ti sọ pe akoba nla ni bijọba apapọ ṣe pawọ mọ owo to yẹ ko maa lọ sasunwọn ijọba ibilẹ kaakiri ipinlẹ Ọṣun.


O ni iwa ọdaju ati iwa ika ni nitori aisan owo naa ti n ṣakoba fun awọn iṣẹ akanṣe tijọba Gomina Ademọla Adeleke dawọle latinu oṣu keji ọdun yii ti wọn ti n fi owo iṣẹ san owo oṣu fawọn oṣiṣẹ.


Tẹ o ba gbagbe, inu oṣu keji ọdun yii ni wahala naa bẹrẹ nigba ti ẹgbẹ.APC gba idajọ kan nile ẹjọ kotẹmilọrun to wa l'Akurẹ, ti wọn si sọ pe kootu ti da awọn alaga atawọn kanselọ ti wọn dibo yan loṣu kẹwaa ọdun 2022 pada si sẹkiteriati.


Ṣugbọn awọn ẹgbẹ PDP sọ pe sakamanje lasan nidajọ naa, wọn tẹ siwaju ninu idibo ijọba ibilẹ lọjọ kejìelogun oṣu keji ọdun yii, ẹgbẹ wọn nikan lo si wọle kaakiri ijọba ibilẹ ọgbọn to wa l'Ọṣun, amọ Gomina Adeleke sọ fun wọn lẹyin ibura pe ki wọn maa ṣiṣẹ latile.


Lasiko rogbodiyan ọhun ni eeyan mẹfa, to fi mọ alaga ijọba ibilẹ Irewọle, Ọnarebu Rẹmi Abass, doloogbe, ti wón si ba ọpọ dukia jẹ.


Latigba naa si ni ẹgbẹ mejeeji ti n ja si iṣakoso kansu, ti awọn oṣiṣẹ NULGE si joko sile.


Ṣugbọn lọsẹ to kọja nijọba ipinlẹ Ọṣun sọrosoke nipasẹ kọmiṣanna fun eto idajọ, Jimi Bada, pe lati oṣu keji ọdun yii lawọn ijọba ibilẹ ko ti ri owo gba, wọn ni ṣe nijọba apapọ gbẹsẹ le owo naa.


Bada, nipasẹ agbẹjọro rẹ, wọ amofin agba lorileede yii, Lateef Fagbemi lọ sile ẹjọ to ga julọ lati ṣalaye iru agbara to ni labẹ ofin lati gbẹsẹ le owo awọn ijọba ibilẹ ti awọn araalu gbe sipo ati lati paṣẹ funjọba apapọ lati yọnda owo naa kiakia.


Nigba to n sọrọ lori ohun to ṣẹlẹ naa, Kọlapọ Alimi ni iyalẹnu lo jẹ pe nnkan ti Aarẹ Bọla Tinubu ja fitafita le lori lasiko to jẹ gomina ipinlẹ Eko lo wa n ṣe funpinlẹ Ọṣun bayii.


O ni lara awọn ti wọn n gba owo oṣu ninu owo kansu ni awọn ori-ade, awọn olukọ ileewe alakọbẹrẹ, awọn oṣiṣẹfẹyinti atawọn oṣiṣẹ kansu funraa wọn.


Bijọba apapọ ba waa kọ, ti wọn ko sanwo naa, tijọba ipinlẹ naa ko si wa wọrọkọ fi ṣe ada lorii rẹ, o di dandan ki ara ni awọn araalu, idi si niyẹn ti Gomina Adeleke fi pinnu lati maa lo owo awọn iṣẹ akanṣe lati fi sanwo naa.


Alimi sọ siwaju pe iwa ika pata ni nnkan tijọba apapọ n ṣe ọhun nitori ko si ile ẹjọ kankan to fun wọn lagbara lati gbẹsẹ le owo to jẹ tipinlẹ Ọṣun nikan laarin gbogbo ipinlẹ to wa lorileede Naijiria.


Amọ ṣa, o ni idi tawọn fi lọ si kootu ni lati ri i pe wọn tete wa ojutu si ọrọ naa, ijọba Adeleke ai gbagbọ pe idajọ ododo yoo fẹsẹ mulẹ.

No comments:

Post a Comment