Ọkunrin onimọ nipa iṣẹ-ọna nni, Yusuf Dongo, ti kede pe oun yoo ṣafihan ere nla ti oun fi irin ṣe nibi ayẹyẹ Ojude-Ọba to maa n waye lọdọọdun niluu Ijẹbu-Ode nipinlẹ Ogun, eleyii ti yoo waye lopin ọsẹ yii.
Yusuf ṣalaye pe odidi ọdun mẹta loun fi ṣe iṣẹ-ọna naa, afojusun rẹ si ni lati ṣagbelarugẹ itan ati aṣa ilẹ Ijẹbu.
Ọmọbibi ilu Ijẹbu-Ode ni Dongo, ẹkọ nipa yiya aworan ati ṣiṣe wọn lọṣọọ, Fine and Applied Arts, lo kọ ni Fasiti Ifẹ.
O ṣalaye pe nibi ayẹyẹ ọdun Ojude-Ọba loun ti fẹẹ ṣafihan ere onirin nla to ni aworan awọn Balogun to ti jẹ kọja atawọn ti wọn wa nibẹ bayii nilẹ Ijẹbu, bẹẹ ni aworan Awujalẹ, ẹni to jẹ ori-ade to pẹ ju lori-itẹ awọn babanla rẹ lorileede Naijiria, wa nibẹ.
Gẹgẹ bo ṣe wi, iṣẹ naa lo fẹẹ fi ṣafihan bi ọdun Ojude-Ọba ṣe ṣe pataki ninu agbende aṣa, o si wa lati ṣe itan ilu Ijẹbu ati ọdun Ojude Ọba lọjọ.
'Ojude Ọba ni ibi pataki lati ṣafihan aworan nla yii. Mo fẹ ki awọn ọmọbibi ilu wa atawọn ajeji mọ nipa aṣa ati itan ilẹ Ijẹbu nipasẹ aworan yii. O jẹ ibi ti a ti maa n ba oniruuru eeyan pade, mo si nigbagbọ pe ọpọlọpọ ibeere ati itakurọsọ ni yoo jẹyọ nipasẹ aworan naa.
Lara awọn ipenija to dojukọ lasiko to n to ere naa jọ, gẹgẹ bi Dongo ṣe sọ, ni bi awọn idile ti wọn wa lara aworan naa ko ṣe tete tẹwọgba erongba rẹ, wiwa awọn akuwori nnkan to fi ṣe e kaakiri latari bi gbogbo nnkan ṣe n fojoojumọ gbowo leri, segesege ina mọnamọna, ati ai si koriya latọdọ awọn araalu titi to fi pari iṣẹ-ọna ọhun.
Dongo, ẹni to ti maa n kopa nibi ayẹyẹ Ojude-Ọba fun aimọye ọdun sẹyin gẹgẹ bii ẹlẹṣin to n ṣojuu idilee Shote Tọwọbọla, sọ pe iriri oun nibi ayẹyẹ naa lo jẹ ki oun ronu lati ṣiṣẹ-ọna nla yii, eleyii to si tobi julọ nipinlẹ Ogun.
No comments:
Post a Comment