Abẹnugan ile igbimọ aṣofin ana nipinlẹ Ọṣun, Hon. Timothy Owoẹyẹ, ti sọ pe ko si aaye fun, yala Gomina Ademọla Adeleke, tabi idile Adeleke lapapọ lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun.
Ṣaaju ni ahesọ ti n lọ kaakiri pe o ṣee ṣe ki Gomina Adeleke darapọ mọ ẹgbẹ APC ṣaaju idibo gomina ti yoo waye lọjọ kẹjọ oṣu kẹjọ ọdun 2026.
Ahesọ yii tun waa rinlẹ si nigba ti fọto kan jade sita nibi ti Gomina Adeleke, ẹgbọn rẹ, Dokita Deji Adeleke ati ọmọ ẹgbọn rẹ, David Adeleke ti gbogbo eeyan mọ si Davido, ti ṣabẹwo sọdọ Aarẹ Bọla Tinubu nipinlẹ Eko lọjọ Tusidee ọsẹ yii.
Bi wọn ṣe n fẹyin kẹẹ ninuu fọto pẹlu aarẹ ni wọn tun ba aya aarẹ, Olurẹmi Tinubu ya fọto, ti ọrọ naa si ti di rannto lori itakun ayelujara kaakiri bayii.
Amọ ṣa, ninu ipade oniroyin kan to waye niluu Oṣogbo lọjọ Wẹsidee ni Owoẹyẹ ti fi ọrọ idile Adeleke we aṣẹwo inu Bibeli to sun le ọmọ tirẹ pa, ṣugbọn to ni ṣe ni ki ọba ge ọmọ ẹnikeji rẹ to wa laaye si meji.
O ni ibẹru ajalu nla to maa de ba Gomina Adeleke ati ẹgbẹ oṣelu PDP ninu idibo to n bọ lọna ọhun lo mu un to fi n gbọn jinnijinni kaakiri ọdọ Aarẹ Tinubu, to si fẹẹ fi agidi darapọ mọ ẹgbẹ APC.
Owoẹyẹ ṣalaye pe ko si nnkan ti Adeleke le ṣe tijọba ko fi nii bọ lọwọ rẹ lọdun 2026 nitori gbogbo ọgbọn janduku ti ẹgbẹ PDP lo lasiko idibo ọdun 2022 ni ko ni le ri lo lọdun to n bọ.
O ke si awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun lati maṣe mikan rara, o ni ko si ọna ẹburu ti Adeleke fẹẹ gba wọnu ẹgbẹ APC ti ko nii ba ijakulẹ pade.
No comments:
Post a Comment