Ọkan lara awọn oṣiṣẹ ajọ Amọtẹkun nipinlẹ Ọṣun, Ogundiran Sheriff, lo ti dagbere faye bayii.
Bii fiimu la gbọ pe ọrọ naa ri lọjọ kẹfa oṣu kẹfa ọdun yii nigba ti ọkunrin naa ṣubu lulẹ lojiji, wọn gbe e digbadigba lọ si ọsibitu lati doola ẹmi rẹ, ṣugbọn ko pẹ rara ti ẹlẹkọ ọrun fi polowo leti ẹ.
Sheriff, gẹgẹ bi alakoso ajọ Amọtẹkun l'Ọṣun, Dokita Adekunle Ọmọyẹle, ṣe ṣalaye, lo jẹ olukọni (Provost) ni B Division ajọ naa to wa niluu Ila-Ọrangun nigba aye rẹ.
Ọmọyẹle ṣapejuwe Sheriff gẹgẹ bii akinkanju, to lo ọgbọn-inu to ni nidi iṣẹ naa lati ri i daju pe alaafia ati ifọkanbalẹ wa niluu Ila Ọrangun.
O ni alafo ti iku rẹ fi silẹ yoo le lati di nitori oṣiṣẹ to ni ikora-ẹni-nijanu, to si maa n fi gbogbo ara ṣiṣẹ ni.
Ọmọyẹle ba awọn mọlébi ọkunrin naa kẹdun iku rẹ, o si ṣeleri pe iṣẹlẹ naa ko nii da omi irẹwẹsi si ọkan awọn ọmọ ajọ Amọtẹkun lori ojuṣe wọn.
No comments:
Post a Comment