Wọn ti kede iku Olori Ṣọlape Christianah Abọlarin, tii ṣe ọkan lara awọn olori Ọrangun Oke-Ila, Ọba (Dokita) Adedokun Abọlarin.
Ọkan lara awọn oloye ilu naa, Oloye Jibọla Awoṣeyi Aṣojuọba lo gbe ikede naa jade, to si ke si gbogbo awọn ọmọ ilu lati ba baba naa kẹdun.
Titi digba ti a n koroyin yii jọ, ko sẹni to mọ ohun to ṣokunfa iku olori to jẹ ọkan lara awọn oṣiṣẹ labẹ ijọba ipinlẹ Ọṣun ọhun.
Ṣugbọn oniruuru ọrọ ibanikẹdun lawọn eeyan kaakiri agbaye ti n kọ sori ikanni ayelujara lati fi kẹdun obinrin oniwa irẹlẹ naa.
Ohun ti a gbọ ni pe ọjọ Mọnde ọsẹ yii niku pa oju obinrin naa de, o si ṣe e ṣe ko ti maa mura silẹ fun ayẹyẹ ọjọọbi rẹ to maa n waye ninu oṣu kẹfa ọdọọdun.
No comments:
Post a Comment