Ọtunba (Dokita) Felix Babatunde Ọbada, ọkọ Erelu Oluṣọla Ọbada to jẹ igbakeji gomina ipinlẹ Ọṣun nigba kan ri, to tun ti figba kan ri jẹ minisita keji fun ọrọ aabo lorileede yii, ti jade laye.
Ọtunba Ọbada lo fi ọpọ ọdun ṣiṣẹ nileefọpo ilẹ wa, NNPP, ko too di alakoso funleeṣẹ Nigeria E-Government Strategies.
Ẹni ọdun mẹtalelaadọrin ni Dokita Ọbada ko too jade laye, iyawo atawọn ọmọ ni wọn n ṣelede lẹyin rẹ.
A gbọ pe awọn mọlẹbi yoo maa kede isinku baba naa laipẹ.
No comments:
Post a Comment