IROYIN YAJOYAJO

Saturday, 7 June 2025

UNIOSUNTH nilo amojuto kiakia, ko si dokita, ko tun si ina ijọba - TOM ke gbajare sijọba Adeleke


The Osun Masterminds (TOM) ti ke si gomina ipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, lati tete wa nnkan ṣe si ọrọ ilewosan UNIOSUN Teaching Hospital to wa niluu Oṣogbo ko too bọ sori.


Nibi ipade oniroyin oloṣooṣu ti ẹgbẹ naa maa n ṣe ni alakoso wọn, Ọjọgbọn Wasiu Oyedokun-Alli ti ka ninu apilẹkọ wọn pe ipo ikaanu ni ọsibitu naa wa, to si ti su awọn araalu ti wọn n lọ sibẹ lati gba iwosan.


Oyedokun-Alli ṣalaye pe pupọ awọn dokita akọṣẹmọṣẹ ti wọn wa nibẹ tẹlẹ ni wọn ti japa, ti ijọba ko si bikita lati gba awọn dokita tuntun sibẹ.


Yatọ si eyi, TOM sọ pe fun ọpọ oṣu sẹyin lawọn ajọ amunawa ti ja ina inu ọsibitu naa, to si jẹ pe bi awọn dokita perete ti wọn ku sibẹ ba lo jẹnẹretọ diẹ, wọn a lo tọọṣi diẹ lati fi da awọn alaisan loun, eleyii to si lewu pupọ.


Wọn ke sijọba lati gba awọn oṣiṣẹ si ọsibitu naa kiakia, bẹrẹ latori awọn alayẹwo, si nọọsi, si dokita atawọn oṣiṣẹ eleto ilera mi-in.


Lori idibo gomina ipinlẹ Ọṣun to n bọ, TOM sọ pe awọn oloṣelu ko gbọdọ fi iṣejọba silẹ, ki wọn maa le ipolongo ibo kaakiri ilu.


Bakan naa lo ke si awọn ẹṣọ alaabo bii ọlọpaa, ọtẹlẹmuyẹ, sifu difẹnsi atawọn amọtẹkun lati tubọ ji giri si iṣẹ wọn, ki wọn maṣe faaye gba awọn adaluru ti wọn maa n wọle ṣaaju idibo nipinlẹ Ọṣun.


TOM parọwa si awọn ọdọ, paapaa, awọn akẹkọọ ti wọn n kawe lawọn ile-ẹkọ giga kaakiri ipinlẹ Ọṣun lati jawọ ninuu lilo egboogi oloro eleyii to ni ipa buburu lori ọjọọwaju wọn.

No comments:

Post a Comment