Ijọba ipinlẹ Ọṣun ti kede bayii pe ko si aaye ọlude, isinmi opin ọsẹ ati iyanṣẹlodi fun awọn oṣiṣẹ ẹka to n ri si ọrọ ilẹ ati aato ilu (Departments of Town Planning and Land Services), mọ.
Ninu atẹjade kan ti Akọwe Agba K. N. Akinlọla fọwọ si fun olori awọn oṣiṣẹ ọba nipinlẹ Ọṣun, lo ti ṣalaye pe igbesẹ naa pọn dandan lati le dẹkun awọn ti wọn maa n lo anfaani asiko naa lati kọle sibi to ba wu wọn.
Akinlọla sọ pe ọpọ araalu ni wọn maa n lo asiko ọlude tabi iyanṣẹlodi ni ẹka naa lati kọ ṣọọbu tabi la oju-ọna si awọn ibi to n da aato ilu ru, to si n fa ọwọ idagbasoke sẹyin nipinlẹ Ọṣun.
O ni iṣẹ ẹka naa ṣe pataki fun imugbooro awujọ, idi si niyẹn ti wọn fi gbọdọ maa wa lẹnu iṣẹ ni gbogbo igba nitori awọn kọlọrọsi ti wọn maa n ṣe n kan to ba wu wọn nigba ti awọn aṣoju ijọba ko ba si nibẹ.
Akinlọla sọ pe ẹka naa ti di ọkan lara awọn ẹka to ṣe pataki ninu iṣẹ ijọba bayii, iyẹn Essential Services, o si ni ki gbogbo awọn oṣiṣẹ ẹka naa kaakiri ijọba ibilẹ ati ijọba ipinlẹ fọkan si ikede yii, bẹẹ ni ki awọn oluśiro-owo lẹkajẹka fi sọkan.
No comments:
Post a Comment