IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 30 September 2025

Ọṣun 2026: Ẹni laya ko waa wọ! Miliọnu lọna aadọta naira ni ẹgbẹ APC yoo ta fọọmu gomina


Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress lorileede yii ti sọ pe miliọna lọna aadọta naira ni ẹnikẹni to ba fẹẹ dupo gomina labẹ ẹgbẹ naa nipinlẹ Ọṣun yoo san.


idibo gomina Ọṣun ni yoo waye lọjọ kẹjọ oṣu Kẹjọ ọdun 2026.


Ninu atẹjade kan ti akọwe ilukooro ẹgbẹ naa, Sulaiman Argungu fi sita laipẹ yii lo ti sọ pe miliọnu mẹwaa naira ni fọọmu fifi erongba han, nigba ti wọn yoo san miliọnu lọna ogoji naira fun fọọmu idije.


O ni fọọmu yii wa fun tita ni lọfiisi ẹgbẹ naa l'Abuja, bẹrẹ lati ọjọ kejila oṣu Kọkanla ọdun yii, ti wọn yoo si da a pada titi di ọjọ kinni oṣu Kejila.

No comments:

Post a Comment