Alaga igbimọ Agba Ọṣun ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, Ẹnjinia Ṣọla Akinwumi, ti dawọọdunnu pẹlu Minisita fun ọrọ okoowo ori-omi lorileede yii Alhaji Isiaka Gboyega Oyetọla, fun ayẹyẹ ọdun kọkanlelaaadọrun to de ori oke eepẹ.
Ninu atẹjade kan ti Ẹnjinia Akinwumi fọwọ si lo ti mọriri oore-ọfẹ Allah lori aye Oyetọla, bẹẹ lo mọriri ipa pataki ti gomina ana nipinlẹ Ọṣun ọhun n ko latigba to ti di aṣiwaju ẹgbẹ APC nipinlẹ Ọṣun.
Wọn gbadura fun ọlọjọọbi pe ki Allah lọọra ẹmi rẹ, ko si tubọ maa darii rẹ ninu idawọle rẹ gbogbo.
No comments:
Post a Comment