Ọkan lara awọn to ti fi erongba han lati du tikẹẹti ẹgbẹ APC fun idibo gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Bọla Oyebamiji, ti sọ pe awọn kan ti n lo orukọ oun lati lu awọn araalu ni jibiti.
Ninu atẹjade kan ti Oyebamiji fi sorii fesibuuku rẹ laipẹ yii lo ti sọ pe nọmba ibanisọrọ +2349061509711 ni awọn onijibiti naa n lo lati fi beere fun iranlọwọ awọn araalu ̀orukọ oun.
Oyebamiji ṣalaye pe oun ko mọ nnkan kan nipa ẹrọ ibanisọrọ naa, jaguda si ni awọn to n lo o lati pe ara wọn ni nnkan ti wọn ko jẹ. O ni oun ko ran ẹnikẹni lati ba awọn eeyan sọrọ; yala fun ti iṣuna tabi ọrọ oṣelu.
O rọ awọn araalu lati maṣe kọbiara si ẹnikẹni to ba fi nọmba naa pe wọn, tabi fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si wọn lorii rẹ.

No comments:
Post a Comment