IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 23 October 2025

Ko śi ọdọ ti ko nii ni iṣẹ gidi lọwọ lasiko iṣejọba mi - BOA


Benedict Gboyega Alabi, ọkan lara awọn oludije funpo gomina ipinlẹ Ọṣun labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, ti sọ pe ọkan pataki lara ohun ti yoo jẹ afojusun iṣejọba oun ni lati ri i daju pe ipese iṣẹ lọpọ yantuuru wa fun awọn ọdọ.


Alabi ṣalaye pe oniruuru ọgbọn atinuda ati ẹbun iyebiye ni Eledua fi jinki awọn ọdọ ipinlẹ Ọṣun, tijọba ba si faaye gba wọn nipa riran iran wọn lọwọ, yoo di nnkan ti yoo wulo pupọ fun araalu.


O sọ siwaju pe ijọba yoo ṣeto ẹkọṣẹ-ọwọ oniruuru fun awọn ọdọ, bẹẹ ni oniruuru eto yoo wa fun awọn aṣẹṣẹjade ileewe girama kaakiri ipinlẹ Ọṣun lati le wulo fun ara wọn ati fun awujọ.


Bakan naa ni Alabi ṣeleri lati jẹ ki awọn ọdọ ni imọ kikun ninu imọ-ẹrọ, idaṣẹsilẹ, okoowo ati bẹẹ bẹẹ lọ lati le din airiṣẹ ṣe ku laarin wọn.


Alabi, ẹni to jẹ igbakeji gomina ipinlẹ Ọṣun ana, fi kun ọrọ rẹ pe ijọba oun yoo ṣagbekalẹ awọn ibudo ti yoo maa yanju aawọ to ba bẹ silẹ lagbegbe kọọkan, iyẹn Peace and Conflict Resolution Centers. O ni nibi ti alaafia ati ifẹ ba wa nikan ni iṣẹ idagbasoke ti le ridi joko.


Alabi sọ pe oun yoo ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn oludaṣẹsilẹ lorileede Naijiria ati loke-okun, lati le jẹ ki wọn waa daṣẹ silẹ l'Ọṣun, ki eto ọrọ-aje le rugọgọ si i.

No comments:

Post a Comment