IROYIN YAJOYAJO

Sunday, 21 December 2025

Gbogbo yin lẹ kunju osunwọn, ṣugbọn a dupẹ pe ẹ faaye gba Oyebamiji - APC


Awọn agbaagba inu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress ni ẹkun idibo Iwọ-oorun Ọṣun, ti dupẹ lọwọ gbogbo awọn to fi erongba han lati dije fun tikẹẹti ẹgbẹ naa fun ifọmọniyanṣe ti wọn ṣafihan rẹ nipa gbigbe Alhaji Bọla Oyebamiji kalẹ.


Nibi ipade ti wọn ṣe niluu Iwo labẹ alaga Ọjọgbọn O.O. Ladipọ ni wọn ti sọ pe gbogbo awọn oludije ọhun ni wọn kunju osunwọn, ti gbogbo aye si da wọn mọ, ṣugbọn ṣe ni wọn gba lati faramọ ohun ti ẹgbẹ maa n fẹ, eyi ti i ṣe fifa ẹnikanṣoṣo silẹ.


Wọn dupẹ fun ipa pataki ti Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, Oloye Bisi Akande, Alhaji Gboyega Oyetọla, Ẹnjinia Sọla Akinwumi, awọn oloye ẹgbẹ APC l'Ọṣun labẹ idari Sooko Tajudeen Lawal atawọn lamẹẹtọ miran, ko lori aṣeyọri naa.+


Wọn dupẹ pataki lọwọ gbogbo awọn oludije lati Iwọ-oorun Ọṣun; Benedict Gboyega Alabi, Ọmọọba Dọtun Babayẹmi, Dokita Akin Ogunbiyi, Sen. Mudasiru Hussain ati Dokita Peter Babalọla, fun bi wọn ṣe faaye gba Oyebamiji.


Wọn gbadura pe ki Ọlọrun san gbogbo wọn lẹsan rere.

No comments:

Post a Comment