IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 25 December 2025

Keresimesi: Gbadebọ Mayọwa Foundation dẹrin pẹẹkẹ awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun


Ko din ni eeyan aadọjọ niluu Ọkinni nijọba ibilẹ Ẹgbẹdọrẹ nipinlẹ Ọṣun to janfaani ayẹwo ilera ọfẹ, ti wọn si tun gba oniruuru ounjẹ lọ sile wọn eleyii ti ajọ Gbadebọ Mayọwa ṣagbatẹru rẹ.


Nigba to n sọrọ nibi eto naa, oludasilẹ ajọ yii, Mayọwa Gbadebọ, sọ pe afojusun oun ni lati maa dẹrin pẹẹkẹ awọn agbalagba lawujọ.


O ni o wu oun ki awọn agbalagba wa nilera pipe, ki wọn si fi idunnu ṣe ọdun, idi si niyẹn ti oun fi gbe eto naa kalẹ.


Gbadebọ sọ siwaju pe ijọba nikan ko le tan iṣoro ilera ati ti ọrọ-aje awọn araalu, oun si n ṣa ipa toun naa nipasẹ ajọ yii lati kin ijọba lọwọ.


O ni ọpọlọpọ awọn eeyan ni wọn n gbẹmi mi lai tii pe ọjọ latari airi itọju to peye lasiko, bẹẹ ni oniruuru arun ti wa lara ẹlomiran ti ko mọ.


Gbadebọ fi kun ọrọ rẹ pe lẹyin ti awọn ṣayẹwo fun awọn agbalagba aadọjọ naa tan lawọn fun wọn ni oogun-oyinbo, ti awọn si tun pin oniruuru ounjẹ bii irẹsi, spaghetti, iyọ, maggi ati bẹẹ bẹẹ lọ fun wọn.


O ni ajọ oun ti figba kan lọ sile awọn ọmọ alailobi, awọn ileewe agbegbe, awọn ọsibitu ati bẹẹ bẹẹ lọ lati nawọ ifẹ si awọn ti wọn nilo iranwọ.


Gbogbo awọn ti wọn janfaani eto naa ni wọn dupẹ lọwọ Gbadebọ fun eto manigbagbe naa.

No comments:

Post a Comment