Alaga Igbimọ Agba Ọṣun ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, Enjinia Ṣọla Akinwumi ti ba awọn mọlẹbi Omọọba Babatunde Pọnnle niluu Ada kẹdun iku baba naa.
Igbimọ naa sọ pe iku Pọnnle, to jẹ oludasilẹ Miccom Golf and Resort, jẹ ẹdun ọkan fun awọn. Yatọ si pe o jẹ ọkọ ọkan lara awọn Igbimọ Agba Ọṣun, iyẹn Oloye Titi Pọnnle, baba yii tun ko ipa manigbagbe ninu idagbasoke ipinlẹ yii nipasẹ oniruuru okoowo to da silẹ.
Akinwumi ranṣẹ ibanikẹdun si aya oloogbe, awọn ọmọ, Kabiesi ilu Ada ati gbogbo awọn ojugba baba to jade laye lẹni ọdun mẹrinlelaadọrun ọhun.
O gbadura pe ki Ọlọrun tu wọn ninu, ko si tẹ baba naa si afẹfẹ rere.

No comments:
Post a Comment