Alaga Igbimọ Agba Ọṣun labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, Ẹnjinia Ṣọla Akinwumi, ti fi ẹmi imoore han lori aṣeyọri idibo abẹle ẹgbẹ naa to waye lọjọ Kẹtala oṣu kejila ọdun yii.
Akinwumi ṣalaye ninu atẹjade kan pe bi eto naa ṣe lọ lalaafia fi han gbogbo agbaye pe ẹgbẹ APC ni ipinnu lati mu ijọba tiwantiwa gbooro lorileede yii.
O gboriyin fun ipa ti Aarẹ Bọla Tinubu, Oloye Bisi Akande, Alhaji Isiaka Gboyega Oyetọla ati gbogbo awọn to fi erongba han lati dije ko lori eto naa.
O ki oludije ti ẹgbẹ APC gbe kalẹ, Alhaji Bọla Munirudeen Oyebamiji, ku oriire, o ni ko si òpè, bẹẹ ni ko si ọ̀ta ninu idibo naa, ohun to kan ni bi ẹgbẹ APC yoo ṣe jawe olubori ninu idibo ọjọ Kẹjọ oṣu kẹjọ ọdun 2026.
Akinwumi rọ gbogbo awọn agbaagba atawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa lati ṣiṣẹ lai kaarẹ laarin awọn ẹgbẹ oṣelu to ku ki ẹgbẹ APC le ṣaṣeyọri ninu idibo naa.

No comments:
Post a Comment