IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 10 December 2025

Ọṣun 2026: Ohunkohun ti ẹgbẹ wa ba sọ ni mo faramọ - Babayẹmi


Ọmọọba Dọtun Babayẹmi ti sọ pe niwọn igba ti oun ti pinnu lati jẹ ọmọ ẹgbẹ onitẹsiwaju, ohunkohun ti ẹgbẹ naa ba sọ lori ọrọ idibo gomina ọdun 2026 nipinlẹ Ọṣun loun faramọ.


Babayẹmi, ẹni to wa laarin awọn oludije meje ti igbimọ ti ẹgbẹ APC gbe kalẹ lati ṣayẹwo awọn mẹsan to fi erongba han lati du tikẹẹti ẹgbẹ naa, ṣalaye pe afojusun ẹgbẹ APC ni lati gba awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun lọwọ iṣejọba buburu, eleyii to si ga ju ifẹ-ọkan ẹnikọọkan lọ.


O ni oun ti lọ kaakiri wọọdu idibo ọọdunrun o din ẹyọkan latigba ti oun ti bẹrẹ igbesẹ yii, nibẹ ni oun si ti n sọ fun awọn araalu nipa ireti ọtun tijọba Aarẹ Bọla Tinubu ko dani, ti oun si n tẹnu mọ ọn fun wọn pe ẹgbẹ lagbara ju ẹnikẹni lọ ati pe oun yoo faramọ gbogbo aṣẹ ti ẹgbẹ ba pa.


Babayẹmi sọ siwaju pe nibi ti ọrọ de bayii, oun mọ pe Aarẹ Tinubu ati gbogbo awọn aṣaaju ẹgbẹ APC ti n gbe igbesẹ lori ọrọ naa lati le ri i daju pe ẹgbẹ naa wa niṣọkan, ki wọn si gbajọba ipinlẹ Ọṣun pada lọdun 2026.

No comments:

Post a Comment