IROYIN YAJOYAJO

Sunday, 14 December 2025

Ọṣun 2026: APC Iwọ-Oorun Ọṣun rọjo adura ranṣẹ lori ọrọ Oyebamiji


Agbarijọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress ni Iwọ-Oorun Ọṣun ti sọ pe idunnu nla lo jẹ fun awọn bi oludije funpo gomina ṣe wa lati iha naa.


Ọjọ Satide to kọja ni gbogbo ẹgbẹ naa fẹnuko gbe Alhaji Munirudeen Bọla Oyebamiji kalẹ bii oludije fun idibo gomina Ọṣun to n bọ lọna.


Ninu atẹjade kan ti alaga wọn, Hon. Ọmọlaoye Olurẹmi Akintọla fi sita ni wọn ti dupẹ lọwọ Aarẹ Bọla Tinubu, Oloye Bisi Akande, Alhaji Gboyega Oyetọla, gbogbo igbimọ iṣakoso ẹgbẹ naa lorileede yii, Oloye Ṣọla Akinwumi to jẹ alaga Igbimọ Agba Ọṣun ati alaga wọn l'Ọṣun, Sooko Tajudeen Lawal.


Bakan naa ni wọn dupẹ lọwọ awọn oludije mẹtala yooku ti wọn jade lati gbogbo ẹkun idibo nipinlẹ Ọṣun fun ifẹ ati igbagbọ ti wọn ni lati ṣatilẹyin fun Alhaji Munirudeen Oyebamiji.


Wọn ni aduroti wọn fihan pe wọn ko jade fun ifẹ ọkan ara wọn, bi ko ṣe fun aṣeyọri ẹgbẹ oṣelu APC l'Ọṣun lọdun 2026, wọn si gbadura pe oju ko nii ti wọn.


Ọmọlaoye ke si gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ lati ṣiṣẹ karakara fun ijawe olubori Oyebamiji ninu idibo gomina ọjọ Kẹjọ oṣu kẹjọ, ọdun 2026.

No comments:

Post a Comment