IROYIN YAJOYAJO

Friday, 12 December 2025

Osun Pathfinder Team ṣeleri atilẹyin fun Gomina Ademọla Adeleke ninu ẹgbẹ Accord


Ẹgbẹ kan to n ṣatilẹyin fun iṣejọba Gomina Ademọla Adeleke nipinlẹ Ọṣun, The Osun Pathfinder Team, ti ki gomina ku oriire fun ijawe olubori rẹ gẹgẹ bii oludije fun ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Accord, wọn ni eleyii jẹ ọpakutẹlẹ si igbega Ọṣun titi di ọdun 2030.


Ninu atẹjade kan ti alakoso wọn, Hon. Diti Aluko ati akọwe, Sọla Akinlẹyẹ, fi sita ni wọn ti gboṣuba fun Gomina Adeleke lori igbesẹ igboya to gbe lati daabo bo ijọba tiwantiwa nipinlẹ Ọṣun kọja ọdun 2026.


Ẹgbẹ naa ṣapejuwe ohun to ṣẹlẹ naa bii igbesẹ manigbagbe eleyii to jẹ ibẹrẹ irinajo oṣelu to nitumọ fun awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun.


Gẹgẹ bi wọn ṣe wi, 'Ẹgbẹ Accord jẹ ọna ti Ọlọrun fẹẹ gba lati le jẹ ki awọn iṣẹ rere Imọlẹ tẹ siwaju, ko si gbooro sii. Labẹ iṣakoso gomina onigboya, to nifẹ awọn araalu, to si fi ilana jijẹ olori to ṣe e mu yangan lelẹ yii, oniruuru iṣẹ idagbasoke lo ti waye l'Ọṣun.


'Oniruuru iṣẹ akanṣe nijọba yii ti ṣe, igbayegbadun awọn oṣiṣẹ jẹ gomina logun, eto ẹkọ to yanrannti, eto ilera to kunju osunwọn, idagbasoke igberiko, ijọba alakoyawọ ati iṣejọba nilana ikanni ayelujara ko gbẹyin, gbogbo eleyii lo gbọdọ tẹ siwaju titi di ọdun 2030.


'Bi gomina ṣe jawe olubori gẹgẹ bii oludije fun ẹgbẹ Accord fi igbẹkẹle ti awọn araalu ni ninu iṣejọba rẹ han, bẹẹ ni wọn fẹ ki gbogbo eleyii tẹ siwaju. Gẹgẹ bii agbekalẹ oṣelu to jẹ olootọ, gbọn-in-gbọn-in ni ẹgbẹ wa, The Pathfinder Team, wa pẹlu Gomina Adeleke lai gbọjẹgẹ ati lai si iyapa.


'A tẹle e titi to fi ṣaṣeyọri lọdun 2022, a tun maa ṣe ju bẹẹ lọ lọdun 2026. A n ṣeleri pe a maa tubọ ṣan ṣokoto akitiyan wa lati fọnrere iṣẹ rere gomina kaakiri ẹsẹkuku ati lati la awọn araalu lọyẹ.


'A n sọ gbangba bayii pe ibikibi ti ọga wa gomina ba ti lọ la maa lọ, ipinnu rẹ ni igbesẹ tiwa, ẹgbẹ oṣelu to ba wa lawa naa maa mule si, ojuṣe gbogbo wa si ni ijawe olubori rẹ.


'Bi a ṣe n lọ sinu ọdun 2026, awa Pathfinder n fi da Gomina Adeleke loju pe digbi la wa lẹyin rẹ. A maa lọ kaakiri wọọdu atijọba ibilẹ lati ri i pe irọrun ni iyansipo rẹ fun saa keji jẹ labẹ asia ẹgbẹ Accord.'


Bakan naa ni alaga fun agbarijọpọ awọn alakoso Pathfinder Team kaakiri ijọba ibilẹ ọgbọn nipinlẹ Ọṣun, Hon. Felix Ọladele, sọ pe ẹgbẹ naa ti ṣetan lati ri i daju pe Gomina Adeleke jawe olubori lọdun 2026 fun itẹsiwwaju oniruuru iṣẹ idagbasoke tiṣejọba rẹ ti dawọ le l'Ọṣun.


Ninu ọrọ tirẹ, alaga igbimọ oludari awọn ọmọ ẹgbẹ Pathfinder, Hon. Lukman Afọlabi, rọ awọn ọmọ ẹgbẹ lati maṣe kaarẹ, ki awọn iṣẹ tijọba Adeleke n ṣe kaakiri Ọṣun bayii si jẹ iwuri fun wọn.

No comments:

Post a Comment