Alaga igbimọ Agba ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress nipinlẹ Ọṣun, Ẹnjinia Ṣọla Akinwumi, ti dawọọdunnu pẹlu gomina ipinlẹ Ọṣun nigba kan ri, Oloye Bisi Akande, fun ayẹyẹ ọdun kẹtadinlaadọrun to pe lori ilẹ alaaye.
Akinwumi sọ ninu atẹjade kan to fọwọ si pe lati nnkan bii aadọta ọdun sẹyin toun ti mọ Oloye Akande, ẹni to jẹ alaga akọkọ fun ẹgbẹ APC, ibaṣepọ to duroore lo wa laarin awọn.
O ni ibi ti Akande ba irinajo aye rẹ de yii, ooreọfẹ nla lo ri gba lọdọ Allah, ọpẹ lo si yẹ ko maa du fun oniruuru aṣeyọri to ti ṣe ninu oṣelu, iṣakoso, fifa ọmọnikeji lọwọ soke ati akọsilẹ iṣejọba to ṣee mu yangan.
O ni ọgbọn inu ati iriri Akande ninu oṣelu lẹkajẹka kọja eyi ti ẹnikẹni le fọwọ rọ sẹyin, eleyii to si jẹ ki awọn araalu ti wọn mọriri rẹ fun un ni inagijẹ "Baba ọmọ kekeke"
Akinwumi tun gboṣuba fun ipa takuntakun ti baba naa ko lasiko ijakadi nla ti wọn fi mu Sẹnetọ Bọla Ahmed Tinubu gẹgẹ bii aarẹ orileede Naijiria, o si gbadura pe ki Ọlọrun tubọ lọọra ẹmi Baba Akande ninu ilera pipe.

No comments:
Post a Comment