Omobinrin akorin ẹmi nni, Bunmi Akinnaanu Adeoye ti gbogbo eeyan mọ si Omije Oju mi, ti jade laye.
Ọsibitu kan niluu Eko la gbọ pe o dakẹ si lalẹ ọjọ Tusidee, ọjọ kẹtala oṣu kinni ọdun yii.
Ọpọlọpọ awọn akẹgbẹẹ rẹ ni wọn ti n ṣedaro rẹ lori itakun ayelujara bayii.
Tẹ o ba gbagbe, ọdun to koja ni fidio kan jade nibi ti wọn ti n ṣadura fun un nileejọsin kan niluu Ibadan.

No comments:
Post a Comment