Ẹgbẹ kan ti ki i ṣe tijọba, World Institute for Peace (WIP), ti kilọ funjọba ipinlẹ Ọṣun lati dẹkun dida si ọrọ ijọba ibilẹ, ki wọn kọju si ojuṣe to jẹ ti wọn.
Alakoso Agba fun ajọ naa, Lamina Kamiludeen, lo sọrọ yii nibi ipade oniroyin kan to waye niluu Oṣogbo laipẹ yii.
O ni ile-ẹjọ Kotẹmilọrun niluu Akurẹ ti yanju ọrọ awọn to jẹ alakoso ijọba ibilẹ l'Ọṣun, kootu si ti fidi rẹ mulẹ pe awọn alaga ati kanselọ ẹgbẹ APC ti wọn dibo yan lọdun 2022 ni wọn lẹtọ lati wa ni kansu.
Kamiludeen tun ran awọn ijọba ipinlẹ Ọṣun leti pe ile-ẹjọ ti dajọ pe ijọba ipinlẹ ko lagbara, bẹẹ ni wọn ko lẹtọọ lati yọ ẹnikẹni ti wọn ba dibo yan si kansu, idajọ naa ko si figba kankan yi pada.
O fi kun ọrọ rẹ pe ijọba ipinlẹ Ọṣun gbọdọ bọwọ fun idajọ ile-ẹjọ to ga julọ lorileede yii, eyi to sọ pe ko si ipinlẹ tabi oṣiṣẹ rẹ kankan to laṣẹ lori owo ijọba ibilẹ.
O ni bijọba ipinlẹ Ọṣun ṣe n lọ lati ile-ẹjọ kan si omiran lori ọrọ owo kansu jẹ aṣilo eto ofin ati mimọ-ọn-mọ fara ni awọn eeyan ẹsẹkuku.
Kamiludeen fi kun ọrọ rẹ pe ẹjọ ti ẹgbẹ oṣelu APP pe, eleyii ti ẹgbẹ PDP rọgbọku le, ko nitumọ mọ nitori ile-ẹjọ Kotẹmilọrun ti yi i danu.
O ni lati ọdun to kọja nijọba apapọ ti yọnda owo awọn ijọba ibilẹ l'Ọṣun, ijọba Gomina Adeleke lo n gbe oniruuru igbesẹ lati ri i pe owo naa ko di sisan fun iwulo awọn ijọba ibilẹ.
O ke sijọba ipinlẹ Ọṣun lati rin ọna to tọ ninu ofin, ki wọn bọwọ fun aṣẹ ile-ẹjọ dipo pipooyi kootu ati pipa irọ fawọn araalu.
O ni ijọba ko gbọdọ fi ọrọ alaafia, idagbasoke ati itọju awọn eeyan ipinlẹ, paapaa, awọn to wa nigberiko, ṣe oṣelu rara.

E ja ki afi Oselu fun awon Oloselu , E ye ganu si Oro Oselu.
ReplyDelete