IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 13 January 2026

Ọṣun 2026: Igbimọ ẹgbẹ APC ni Iwọ-Oorun Ọṣun ṣabẹwo sọdọ Peter Babalọla


Igbimọ ti awọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress ni Iwọ-Oorun ipinlẹ Ọṣun gbe kalẹ lati ba awọn to fi erongba han lati dije funpo gomina ninu ẹgbẹ naa sọrọ lẹyin ti wọn ti fa Alhaji Bọla Oyebamiji kalẹ, ti ṣabẹwo sọdọ Dokita Peter Adebayọ Babalọla.


Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ Kejila oṣu Kinni ọdun yii ni wọn lọ sile rẹ niluu Oṣogbo, gẹgẹ bi alaga wọn, Honourable Ọmọlaoye O. Akintọla, ṣe ṣalaye.


Ọmọlaoye sọ pe awọn pinnu lati kọkọ lọ sọdọ awọn oludije mẹfẹẹfa ti wọn wa lati iha Iwọ-Oorun Ọṣun nitori ile la tii kẹṣọ rode. O ni abẹwo naa si so eso rere pupọ.


Ninu ọrọ Dokita Peter Babalola, o dupẹ fun bi awọn igbimọ naa ṣe ka a si lati ṣabẹwo sọdọ rẹ. O ni o pọn dandan ki wọn lọ kaakiri lati ba awọn ti inu ba n bi sọrọ fun aṣeyọri idibo oṣu kẹjọ, ki wọn si ri i daju pe onikaluku jẹ nibi ti wọn ba ṣe si.


Awọn igbimọ naa wa dupẹ lọwọ Babalọla fun ọgbọn agba ati ọkan ifẹ to ni lati ri i daju pe ẹgbẹ naa rọwọ mu ninu idibo gomina ọdun 2026.

No comments:

Post a Comment