IROYIN YAJOYAJO

Friday, 27 February 2026

Adeleke kede igba ti awọn olukọ tuntun yoo bẹrẹ iṣẹ l'Ọṣun


Gomina Ademọla Adeleke ti kede pe iṣi-kinni awọn olukọ tuntun tijọba oun gba yoo bẹrẹ iṣẹ lọjọ kinni, oṣu Kẹta ọdun yii.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ fun gomina, Ọlawale Rasheed, fi sita lo ti sọ pe ninu ipade awọn ọmọ igbimọ alaṣẹ ipinlẹ Ọṣun to waye lọjọ Tọsidee ni wọn ti fẹnu ọrọ yii ko.

Ọlawale ṣalaye pe awọn igbimọ ọhun ti sọ fun kọmiṣanna fun eto-ẹkọ lati ri i pe igbesẹ naa yọri kiakia.

Bakan naa ni wọn gbe igbimọ kan kalẹ lati ṣewadii oniruuru awuyewuye to n waye lori ọrọ lọbalọba nipinlẹ Ọṣun.

No comments:

Post a Comment